-
Nọ́ńbà 32:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Mósè dá wọn lóhùn pé: “Tí ẹ bá lè ṣe èyí: Kí ẹ gbé ohun ìjà yín níwájú Jèhófà láti jagun+ náà; 21 tí gbogbo yín bá sì gbé ohun ìjà, tí ẹ sọdá Jọ́dánì níwájú Jèhófà nígbà tó ń lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀,+ 22 títí a fi máa gba ilẹ̀ náà níwájú Jèhófà,+ nígbà náà, ẹ lè pa dà,+ ẹ ò sì ní jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ yìí á wá di tiyín níwájú Jèhófà.+
-
-
Nọ́ńbà 32:25-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì wá dá Mósè lóhùn pé: “Ohun tí olúwa mi pa láṣẹ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ máa ṣe gẹ́lẹ́. 26 Àwọn ọmọ wa, àwọn ìyàwó wa, àwọn àgbo ẹran wa àti gbogbo ẹran ọ̀sìn wa máa wà ní àwọn ìlú Gílíádì,+ 27 àmọ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ máa sọdá, gbogbo ọkùnrin tó dira ogun láti lọ jagun níwájú Jèhófà,+ bí olúwa mi ṣe sọ.”
28 Mósè wá pàṣẹ fún àlùfáà Élíásárì nípa wọn, fún Jóṣúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nínú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 29 Mósè sọ fún wọn pé: “Tí àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì bá bá yín sọdá Jọ́dánì, tí gbogbo ọkùnrin sì dira ogun níwájú Jèhófà, tí ẹ sì ṣẹ́gun ilẹ̀ náà, kí ẹ wá fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì kó lè di tiwọn.+
-