10 Àti pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Olúwa, o fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 11 Wọ́n á ṣègbé, àmọ́ ìwọ á máa wà nìṣó; gbogbo wọn á sì gbó bí aṣọ, 12 o máa ká wọn jọ bí aṣọ àwọ̀lékè, a sì máa pààrọ̀ wọn bí aṣọ. Àmọ́ ìwọ ò yí pa dà, àwọn ọdún rẹ ò sì ní dópin láé.”+