ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 93:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Tipẹ́tipẹ́ ni ìtẹ́ rẹ ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in;+

      O ti wà láti ayébáyé.+

  • Àìsáyà 40:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Ṣé o ò mọ̀ ni? Ṣé o ò tíì gbọ́ ni?

      Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ayé, jẹ́ Ọlọ́run títí ayé.+

      Kì í rẹ̀ ẹ́, okun rẹ̀ kì í sì í tán.+

      Àwámáridìí ni òye rẹ̀.*+

  • Hábákúkù 1:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà, ṣebí láti ayérayé ni ìwọ ti wà?+

      Ọlọ́run mi, Ẹni Mímọ́ mi, ìwọ kì í kú.*+

      Jèhófà, ìwọ lo yàn wọ́n láti ṣèdájọ́;

      Àpáta mi,+ o lò wọ́n láti fìyà jẹni.*+

  • 1 Tímótì 1:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nítorí náà, kí ọlá àti ògo máa jẹ́ ti Ọba ayérayé,+ ẹni tí kò lè díbàjẹ́,+ tí a kò lè rí,+ Ọlọ́run kan ṣoṣo,+ títí láé àti láéláé. Àmín.

  • Ìfihàn 1:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Jèhófà* Ọlọ́run sọ pé, “Èmi ni Ááfà àti Ómégà,*+ Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀, Olódùmarè.”+

  • Ìfihàn 15:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Wọ́n ń kọ orin Mósè+ ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, pé:

      “Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.+ Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ,+ Ọba ayérayé.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́