-
Nehemáyà 9:33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 O ò lẹ́bi kankan nínú gbogbo ohun tó dé bá wa, nítorí òótọ́ lo fi bá wa lò; àwa la hùwà burúkú.+
-
-
Sáàmù 59:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́ ní tèmi, màá kọrin nípa okun rẹ;+
Ní àárọ̀, màá fi ìdùnnú sọ nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
-
-
Dáníẹ́lì 9:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, àmọ́ àwa ni ìtìjú bá, bó ṣe rí lónìí yìí, àwa èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn tó wà nítòsí àti lọ́nà jíjìn, ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí torí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.+
-