ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 11:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+

      Ìtẹ́ Jèhófà wà ní ọ̀run.+

      Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ tó rí ohun gbogbo* ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ èèyàn.+

  • Sáàmù 33:13-15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Jèhófà bojú wolẹ̀ láti ọ̀run;

      Ó ń rí gbogbo ọmọ èèyàn.+

      14 Láti ibi tó ń gbé,

      Ó ń wo gbogbo àwọn tó ń gbé ayé.

      15 Òun ló ń mọ ọkàn gbogbo èèyàn bí ẹni mọ ìkòkò;

      Ó ń gbé gbogbo iṣẹ́ wọn yẹ̀ wò.+

  • Jeremáyà 16:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nítorí ojú mi wà lára gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.*

      Wọn ò pa mọ́ lójú mi,

      Bẹ́ẹ̀ ni àṣìṣe wọn kò ṣókùnkùn sí mi.

  • Jeremáyà 23:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 “Ṣé ibì kan wà téèyàn lè sá pa mọ́ sí tí mi ò ní lè rí i?”+ ni Jèhófà wí.

      “Ǹjẹ́ ohunkóhun wà láyé tàbí lọ́run tí ojú mi ò tó?”+ ni Jèhófà wí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́