ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 13:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Kí ẹ sì sọ fún ọmọ yín ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Torí ohun tí Jèhófà ṣe fún mi nígbà tí mo kúrò ní Íjíbítì ni.’+

  • 1 Kíróníkà 29:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Nígbà náà, Dáfídì yin Jèhófà lójú gbogbo ìjọ náà. Dáfídì sọ pé: “Ìyìn ni fún ọ, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì baba wa, títí láé àti láéláé.* 11 Jèhófà, tìrẹ ni títóbi+ àti agbára ńlá+ àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá,*+ nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ.+ Jèhófà, tìrẹ ni ìjọba.+ Ìwọ ni Ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe olórí lórí ohun gbogbo.

  • Sáàmù 78:2-4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Màá la ẹnu mi láti pa òwe.

      Màá pa àwọn àlọ́ tó ti wà tipẹ́tipẹ́.+

       3 Àwọn ohun tí a ti gbọ́ tí a sì mọ̀,

      Èyí tí àwọn bàbá wa sọ fún wa,+

       4 A ò ní fi wọ́n pa mọ́ fún àwọn ọmọ wọn;

      A ó ròyìn fún ìran tó ń bọ̀+

      Nípa àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ fún ìyìn àti nípa agbára rẹ̀,+

      Àwọn ohun àgbàyanu tó ti ṣe.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́