ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 7:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Tí àwọn ọmọ Kénáánì àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà bá gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n á yí wa ká, wọ́n á sì pa orúkọ wa rẹ́ kúrò ní ayé, kí lo máa wá ṣe nípa orúkọ ńlá rẹ?”+

  • 1 Sámúẹ́lì 12:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Jèhófà kò ní kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀+ nítorí orúkọ ńlá rẹ̀+ àti nítorí pé Jèhófà ti pinnu láti fi yín ṣe èèyàn rẹ̀.+

  • 2 Kíróníkà 14:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ásà wá ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. + Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé,*+ a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.+ Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí rẹ.”+

  • Sáàmù 115:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 115 Kì í ṣe àwa, Jèhófà, kì í ṣe àwa,*

      Àmọ́ orúkọ rẹ ni ògo yẹ+

      Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ.+

       2 Ṣé ó yẹ kí àwọn orílẹ̀-èdè sọ pé:

      “Ọlọ́run wọn dà?”+

  • Àìsáyà 48:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Àmọ́ nítorí orúkọ mi, mi ò ní bínú mọ́;+

      Nítorí ìyìn mi, màá kó ara mi níjàánu lórí ọ̀rọ̀ rẹ,

      Mi ò sì ní pa ọ́ run.+

  • Jeremáyà 14:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà wa jẹ́rìí sí i pé a ti ṣe àṣìṣe,

      Jèhófà, ràn wá lọ́wọ́ nítorí orúkọ rẹ.+

      Nítorí ìwà àìṣòótọ́ wa pọ̀,+

      Ìwọ sì ni a dẹ́ṣẹ̀ sí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́