-
Ẹ́kísódù 34:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, 7 tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini,+ àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.”+
-
-
Diutarónómì 7:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 O mọ̀ dáadáa pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run tó ṣeé fọkàn tán, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn títí dé ẹgbẹ̀rún ìran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+
-