-
Sáàmù 78:43-51Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Bó ṣe fi àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ hàn ní Íjíbítì+
Àti àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní agbègbè Sóánì,
44 Àti bó ṣe sọ àwọn ipa odò Náílì di ẹ̀jẹ̀,+
Tí wọn ò fi lè mu omi àwọn odò wọn.
46 Ó fi àwọn ohun ọ̀gbìn wọn fún àwọn ọ̀yánnú eéṣú,
Ó sì fi èso iṣẹ́ wọn fún ọ̀wọ́ eéṣú.+
47 Ó fi yìnyín pa àjàrà wọn run,+
Ó sì fi àwọn òkúta yìnyín pa àwọn igi síkámórè wọn.
49 Ó tú ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lé wọn lórí,
Ìbínú ńlá àti ìrunú àti wàhálà,
Ó rán àwùjọ àwọn áńgẹ́lì láti mú àjálù wá.
50 Ó la ọ̀nà fún ìbínú rẹ̀.
51 Níkẹyìn, ó pa gbogbo àkọ́bí Íjíbítì,+
Ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ wọn nínú àwọn àgọ́ Hámù.
-