ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 4:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Àbí Ọlọ́run ti gbìyànjú láti mú orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ látinú orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú àwọn ìdájọ́,* àmì, iṣẹ́ ìyanu,+ ogun,+ pẹ̀lú ọwọ́ agbára,+ apá tó nà jáde, tó sì ṣe àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe fún yín ní Íjíbítì níṣojú yín?

  • Nehemáyà 9:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 O wá ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti fìyà jẹ Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ rẹ̀,+ torí o mọ̀ pé wọ́n ti kọjá àyè wọn+ sí àwọn èèyàn rẹ. O ṣe orúkọ fún ara rẹ, orúkọ náà sì wà títí dòní.+

  • Sáàmù 105:27-36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ láàárín wọn,

      Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hámù.+

      28 Ó rán òkùnkùn, ilẹ̀ náà sì ṣókùnkùn;+

      Wọn kò ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

      29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,

      Ó sì pa ẹja wọn.+

      30 Àwọn àkèré ń gbá yìn-ìn ní ilẹ̀ wọn,+

      Kódà nínú àwọn yàrá ọba.

      31 Ó pàṣẹ pé kí àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ ya wọlé,

      Kí kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.+

      32 Ó sọ òjò wọn di yìnyín,

      Ó sì rán mànàmáná* sí ilẹ̀ wọn.+

      33 Ó kọ lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,

      Ó sì ṣẹ́ àwọn igi tó wà ní ilẹ̀ wọn sí wẹ́wẹ́.

      34 Ó ní kí àwọn eéṣú ya wọlé,

      Àwọn ọmọ eéṣú tí kò níye.+

      35 Wọ́n jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà,

      Wọ́n sì jẹ irè oko wọn.

      36 Lẹ́yìn náà, ó pa gbogbo àkọ́bí tó wà ní ilẹ̀ wọn,+

      Ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́