44 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín,+ kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín,+45 kí ẹ lè fi hàn pé ọmọ Baba yín tó wà ní ọ̀run lẹ jẹ́,+ torí ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.+
17 bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn+ ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde,+ ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”+
17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé wá láti òkè,+ ó ń wá látọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,+ ẹni tí kì í yí pa dà, tí kì í sì í sún kiri bí òjìji.*+