ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 31:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Ìwọ ni àpáta mi àti ibi ààbò mi;+

      Wàá darí mi,+ wàá sì ṣamọ̀nà mi, nítorí orúkọ rẹ.+

  • Sáàmù 79:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run ìgbàlà wa,+

      Nítorí orúkọ rẹ ológo;

      Gbà wá sílẹ̀, kí o sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá* nítorí orúkọ rẹ.+

  • Sáàmù 109:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Àmọ́ ìwọ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,

      Gbèjà mi nítorí orúkọ rẹ.+

      Gbà mí sílẹ̀, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára.+

  • Sáàmù 143:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Jèhófà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n máa wà láàyè nítorí orúkọ rẹ.

      Gbà mí* nínú wàhálà nítorí òdodo rẹ.+

  • Ìsíkíẹ́lì 36:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 “Torí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ilé Ísírẹ́lì, kì í ṣe torí yín ni mo ṣe gbé ìgbésẹ̀, àmọ́ torí orúkọ mímọ́ mi ni, èyí tí ẹ kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ lọ.”’+

  • Dáníẹ́lì 9:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Jèhófà, jọ̀ọ́ tẹ́tí gbọ́. Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì.+ Jèhófà, jọ̀ọ́ fiyè sí wa, kí o sì gbé ìgbésẹ̀! Má ṣe jẹ́ kó pẹ́, torí tìẹ, Ọlọ́run mi, torí orúkọ rẹ la fi pe ìlú rẹ àti àwọn èèyàn rẹ.”+

  • Mátíù 6:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 “Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí:+

      “‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ+ rẹ di mímọ́.*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́