19 màá sì sọ fún ara mi pé: “O ní ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí mo ti tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fọkàn balẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn ara ẹ.”’ 20 Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé, ‘Aláìlóye, òru òní ni wọ́n máa béèrè ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ló máa wá ni àwọn ohun tí o ti tò jọ?’+