ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 49:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé àwọn ọlọ́gbọ́n pàápàá ń kú;

      Àwọn òmùgọ̀ àti àwọn aláìnírònú ń ṣègbé pa pọ̀,+

      Wọ́n á sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì.+

  • Oníwàásù 2:18, 19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Mo wá kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,*+ torí mo gbọ́dọ̀ fi í sílẹ̀ fún ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi.+ 19 Ta ló sì mọ̀ bóyá ó máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀?+ Síbẹ̀, òun ni yóò máa darí gbogbo ohun tí mo ti fi akitiyan àti ọgbọ́n kó jọ lábẹ́ ọ̀run.* Asán ni èyí pẹ̀lú.

  • Oníwàásù 4:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ọkùnrin kan wà tó dá wà, kò ní ẹnì kejì; kò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ará, àmọ́ iṣẹ́ àṣekára tó ń ṣe kò lópin. Ojú rẹ̀ kò kúrò nínú kíkó ọrọ̀ jọ.+ Àmọ́, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bi ara rẹ̀ pé, ‘Ta ni mò ń tìtorí rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára tí mo sì ń fi àwọn ohun rere du ara mi’?+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ó sì jẹ́ iṣẹ́ tó ń tánni lókun.+

  • Lúùkù 12:19, 20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 màá sì sọ fún ara* mi pé: “O ní* ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí mo ti tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fọkàn balẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn ara ẹ.”’ 20 Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé, ‘Aláìlóye, òru òní ni wọ́n máa béèrè ẹ̀mí* rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ló máa wá ni àwọn ohun tí o ti tò jọ?’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́