ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 21:20, 21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Áhábù sọ fún Èlíjà pé: “O ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi!”+ Ó dáhùn pé: “Mo ti wá ọ kàn. ‘Nítorí o ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ 21 màá mú àjálù bá ọ, màá gbá ọ dà nù bí ẹni gbálẹ̀, màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run,+ títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+

  • 2 Àwọn Ọba 10:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Torí náà, ẹ mọ̀ dájú pé kò sí ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Jèhófà kéde sórí ilé Áhábù tí kò ní ṣẹ,*+ Jèhófà sì ti ṣe ohun tó gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà sọ.”+ 11 Yàtọ̀ síyẹn, Jéhù pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Jésírẹ́lì, títí kan gbogbo sàràkí ọkùnrin rẹ̀, àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ àti àwọn àlùfáà rẹ̀,+ kò jẹ́ kí èèyàn rẹ̀ kankan ṣẹ́ kù.+

  • Jeremáyà 22:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà wí, ‘kódà bí Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà, bá tiẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ibẹ̀ ni màá ti yọ ọ́ kúrò!

  • Jeremáyà 22:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

      ‘Ẹ kọ ọ́ sílẹ̀ pé ọkùnrin yìí kò bímọ,

      Pé ọkùnrin yìí kò ní ṣe àṣeyọrí kankan jálẹ̀ ayé rẹ̀,*

      Nítorí kò sí ìkankan nínú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tó máa ṣàṣeyọrí

      Láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì kí ó sì ṣàkóso ní Júdà lẹ́ẹ̀kan sí i.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́