ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 13:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Bábílónì tó lógo* jù nínú àwọn ìjọba,+

      Ẹwà àti ògo àwọn ará Kálídíà,+

      Máa dà bíi Sódómù àti Gòmórà nígbà tí Ọlọ́run bì wọ́n ṣubú.+

  • Àìsáyà 14:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 o máa pa òwe* yìí sí ọba Bábílónì pé:

      “Ẹ wo bí òpin ṣe dé bá ẹni tó ń fipá kó àwọn míì ṣiṣẹ́!

      Ẹ wo bí ìfìyàjẹni ṣe wá sí òpin!+

  • Àìsáyà 45:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 45 Ohun tí Jèhófà sọ fún ẹni tó yàn nìyí, fún Kírúsì,+

      Ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú,+

      Láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀,+

      Láti gba ohun ìjà* àwọn ọba,

      Láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀,

      Kí wọ́n má sì ti àwọn ẹnubodè:

  • Jeremáyà 51:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Lójijì, Bábílónì ṣubú, ó sì fọ́.+

      Ẹ pohùn réré ẹkún fún un! +

      Ẹ fún un ní básámù nítorí ìrora rẹ̀; bóyá ara rẹ̀ máa yá.”

  • Dáníẹ́lì 5:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 “PÉRÉSÌ, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà.”+

  • Dáníẹ́lì 5:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Òru ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n pa Bẹliṣásárì, ọba àwọn ará Kálídíà.+

  • Ìfihàn 14:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Áńgẹ́lì kejì tẹ̀ lé e, ó ń sọ pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá+ ti ṣubú,+ ẹni tó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* ti ìṣekúṣe* rẹ̀!”+

  • Ìfihàn 18:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Ó sì fi ohùn tó le ké jáde pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú,+ ó sì ti di ibi tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbé àti ibi tí gbogbo ẹ̀mí àìmọ́* àti gbogbo ẹyẹ àìmọ́ tí a kórìíra ń lúgọ sí!+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́