-
Ìfihàn 18:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ó sì fi ohùn tó le ké jáde pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú,+ ó sì ti di ibi tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbé àti ibi tí gbogbo ẹ̀mí àìmọ́* àti gbogbo ẹyẹ àìmọ́ tí a kórìíra ń lúgọ sí!+ 3 Gbogbo orílẹ̀-èdè ti kó sọ́wọ́ rẹ̀ torí wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* ti ìṣekúṣe* rẹ̀,+ àwọn ọba ayé sì bá a ṣe ìṣekúṣe,+ àwọn oníṣòwò* ayé sì di ọlọ́rọ̀ torí ó ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ lọ́nà tó bùáyà, kò sì nítìjú.”
-