20 Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì lọ sí aginjù Tékóà.+ Bí wọ́n ṣe ń lọ, Jèhóṣáfátì dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ gbọ́ mi, Júdà àti ẹ̀yin tó ń gbé Jerúsálẹ́mù! Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín kí ẹ lè dúró gbọn-in gbọn-in. Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀,+ ẹ ó sì ṣàṣeyọrí.”