-
2 Àwọn Ọba 17:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Wọ́n ń gbé àwọn ọwọ̀n òrìṣà àti àwọn òpó òrìṣà*+ kalẹ̀ fún ara wọn lórí gbogbo òkè àti lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀;+ 11 orí gbogbo ibi gíga wọ̀nyí ni wọ́n ti ń mú ẹbọ rú èéfín bí àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé kúrò níwájú wọn lọ sí ìgbèkùn.+ Wọ́n ń fi ohun búburú tí wọ́n ṣe mú Jèhófà bínú.
12 Wọ́n ń sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin,*+ èyí tí Jèhófà sọ fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan yìí!”+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 20:28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Mo mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún wọn.+ Nígbà tí wọ́n rí gbogbo òkè tó ga àti àwọn igi tí ewé kún orí rẹ̀,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ wọn, wọ́n sì ń mú àwọn ọrẹ wọn tó ń múnú bí mi lọ síbẹ̀. Wọ́n ń gbé àwọn ẹbọ wọn tó ní òórùn dídùn* lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń da àwọn ọrẹ ohun mímu wọn sílẹ̀ níbẹ̀.
-