17 Àmọ́ ó wò wọ́n tààràtà, ó sì sọ pé: “Kí wá ni èyí túmọ̀ sí, ohun tí a kọ pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé’?*+
33 bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Wò ó! Màá fi òkúta+ ìkọ̀sẹ̀ kan àti àpáta agbéniṣubú lélẹ̀ ní Síónì, àmọ́ ẹni tó bá gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e kò ní rí ìjákulẹ̀.”+
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ló ṣe iyebíye fún, torí ẹ jẹ́ onígbàgbọ́; àmọ́ fún àwọn tí kò gbà gbọ́, “òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀,+ òun ló wá di olórí òkúta igun ilé”*+