ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 118:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀

      Ti di olórí òkúta igun ilé.*+

  • Àìsáyà 28:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

      “Wò ó, màá fi òkúta+ tí a ti dán wò ṣe ìpìlẹ̀ ní Síónì,

      Òkúta igun ilé+ tó ṣeyebíye, ti ìpìlẹ̀ tó dájú.+

      Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ kò ní bẹ̀rù.+

  • Mátíù 21:42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 42 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì kà á nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé.*+ Ọ̀dọ̀ Jèhófà* ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?+

  • Mátíù 21:44
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 44 Bákan náà, ẹni tó bá kọ lu òkúta yìí máa fọ́ túútúú.+ Tó bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, ó máa rún ẹni náà wómúwómú.”+

  • Máàkù 12:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ṣé ẹ ò ka ìwé mímọ́ yìí rí ni, pé: ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé.*+ 11 Ọ̀dọ̀ Jèhófà* ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?”+

  • Ìṣe 4:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Jésù yìí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin kọ́lékọ́lé ò kà sí tó ti wá di olórí òkúta igun ilé.’*+

  • 1 Pétérù 2:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Nítorí náà, ẹ̀yin ló ṣe iyebíye fún, torí ẹ jẹ́ onígbàgbọ́; àmọ́ fún àwọn tí kò gbà gbọ́, “òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀,+ òun ló wá di olórí òkúta igun ilé”*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́