-
Mátíù 13:18-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Ní báyìí, ẹ fetí sí àpèjúwe ọkùnrin tó fún irúgbìn.+ 19 Tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà, àmọ́ tí kò yé e, ẹni burúkú náà+ á wá, á sì já ohun tí a gbìn sínú ọkàn rẹ̀ gbà lọ; èyí ni irúgbìn tó bọ́ sí etí ọ̀nà.+ 20 Ní ti èyí tó bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tó sì fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 21 Síbẹ̀, kò ta gbòǹgbò nínú rẹ̀, àmọ́ ó ń bá a lọ fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni a mú un kọsẹ̀. 22 Ní ti èyí tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí*+ àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso.+ 23 Ní ti èyí tó bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tó sì ń yé e, tó so èso lóòótọ́, tó sì ń mú èso jáde, eléyìí so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ìyẹn ọgọ́ta (60), òmíràn ọgbọ̀n (30).”+
-
-
Máàkù 4:14-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “Afúnrúgbìn fún irúgbìn ọ̀rọ̀ náà.+ 15 Torí náà, àwọn yìí ni àwọn tó bọ́ sí etí ọ̀nà, níbi tí a gbin ọ̀rọ̀ náà sí; àmọ́ gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ, Sátánì wá,+ ó sì mú ọ̀rọ̀ tí a gbìn sínú wọn kúrò.+ 16 Bákan náà, àwọn yìí ló bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta; gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á.+ 17 Síbẹ̀, wọn ò ta gbòǹgbò nínú ara wọn, àmọ́ wọ́n ń bá a lọ fúngbà díẹ̀; gbàrà tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n kọsẹ̀. 18 Àwọn míì wà tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún. Àwọn yìí ló ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,+ 19 àmọ́ àníyàn+ ètò àwọn nǹkan yìí,* agbára ìtannijẹ ọrọ̀+ àti ìfẹ́ + gbogbo nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn, wọ́n fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso. 20 Níkẹyìn, àwọn tó bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa ni àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n fi ọkàn rere gbà á, tí wọ́n sì ń so èso ní ìlọ́po ọgbọ̀n (30), ọgọ́ta (60) àti ọgọ́rùn-ún (100).”+
-