-
Máàkù 6:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ó wá pe àwọn Méjìlá náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rán wọn jáde ní méjì-méjì,+ ó sì fún wọn láṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́.+ 8 Ó tún pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe gbé ohunkóhun dání fún ìrìn àjò náà, àfi ọ̀pá, kí wọ́n má ṣe gbé oúnjẹ àti àpò oúnjẹ, kí wọ́n má sì kó owó* sínú àmùrè owó wọn,+ 9 àmọ́ kí wọ́n wọ bàtà, kí wọ́n má sì wọ aṣọ méjì.*
-