11 Torí ìrora rẹ̀, ó máa rí i, ó sì máa tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Nípasẹ̀ ìmọ̀ rẹ̀, ìránṣẹ́ mi+ tó jẹ́ olódodo
Máa mú kí a ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sí olódodo,+
Ó sì máa ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+
12 Torí ìyẹn, màá fún un ní ìpín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀,
Ó sì máa pín ẹrù ogun pẹ̀lú àwọn alágbára,
Torí ó tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde, àní títí dé ikú,+
Wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀;+
Ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn,+
Ó sì bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ̀bẹ̀.+