-
Ìfihàn 13:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ó sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún gbogbo èèyàn—ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ẹni tó wà lómìnira àti ẹrú—pé kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn,+ 17 àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà, orúkọ+ ẹranko náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.+ 18 Ibi tó ti gba ọgbọ́n nìyí: Kí ẹni tó ní òye ṣírò nọ́ńbà ẹranko náà, torí pé nọ́ńbà èèyàn ni,* nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666).+
-
-
Ìfihàn 20:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Mo rí àwọn ìtẹ́, a sì fún àwọn tó jókòó sórí wọn ní agbára láti ṣèdájọ́. Kódà, mo rí ọkàn* àwọn tí wọ́n pa* torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jésù, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko náà tàbí ère rẹ̀, tí wọn ò sì gba àmì náà síwájú orí wọn àti ọwọ́ wọn.+ Wọ́n pa dà wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kristi+ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.
-