-
Mátíù 10:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) náà nìyí:+ Àkọ́kọ́, Símónì, tí wọ́n ń pè ní Pétérù+ àti Áńdérù+ arákùnrin rẹ̀; Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù+ arákùnrin rẹ̀; 3 Fílípì àti Bátólómíù;+ Tọ́másì+ àti Mátíù+ agbowó orí; Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì; àti Tádéọ́sì; 4 Símónì tó jẹ́ Kánánéánì;* àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó dalẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.+
-
-
Lúùkù 6:13-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì yan méjìlá (12) lára wọn, ó tún pè wọ́n ní àpọ́sítélì,+ àwọn ni: 14 Símónì, tó tún pè ní Pétérù, Áńdérù arákùnrin rẹ̀, Jémíìsì, Jòhánù, Fílípì,+ Bátólómíù, 15 Mátíù, Tọ́másì,+ Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Símónì tí wọ́n ń pè ní “onítara,” 16 Júdásì ọmọ Jémíìsì àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó di ọ̀dàlẹ̀.
-