ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Àgọ́ ìjọsìn, ibi tí wọ́n ti ń rúbọ (1-9)

      • Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ (10-14)

      • Ìlànà nípa àwọn ẹran tó ti kú (15, 16)

Léfítíkù 17:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 3:1, 2; 7:11

Léfítíkù 17:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 3:3-5; 7:29-31

Léfítíkù 17:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ewúrẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:17; Joṣ 24:14
  • +Ẹk 34:15; Di 31:16

Léfítíkù 17:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:3; Di 12:5, 6, 13, 14

Léfítíkù 17:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:4; Le 3:17; 7:26; 19:26; 1Sa 14:33; Iṣe 15:20, 29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 39

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2014, ojú ìwé 10-11

    6/15/1991, ojú ìwé 9

Léfítíkù 17:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:14; Di 12:23
  • +Le 8:15; 16:18
  • +Mt 26:28; Ro 3:25; 5:9; Ef 1:7; Heb 9:22; 13:12; 1Pe 1:2; 1Jo 1:7; Ifi 1:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 75

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2004, ojú ìwé 15

    6/15/1991, ojú ìwé 9

Léfítíkù 17:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn kankan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:49
  • +Di 12:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2004, ojú ìwé 15

Léfítíkù 17:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:16; 15:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Kọ́ Wa, ojú ìwé 139

    Bíbélì Fi Kọ́ni, ojú ìwé 129

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2004, ojú ìwé 15

    10/15/2000, ojú ìwé 30-31

Léfítíkù 17:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 39

Léfítíkù 17:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:31; Di 14:21
  • +Le 11:40

Léfítíkù 17:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wẹ ẹran ara rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 19:20

Àwọn míì

Léf. 17:5Le 3:1, 2; 7:11
Léf. 17:6Le 3:3-5; 7:29-31
Léf. 17:7Di 32:17; Joṣ 24:14
Léf. 17:7Ẹk 34:15; Di 31:16
Léf. 17:9Le 1:3; Di 12:5, 6, 13, 14
Léf. 17:10Jẹ 9:4; Le 3:17; 7:26; 19:26; 1Sa 14:33; Iṣe 15:20, 29
Léf. 17:11Le 17:14; Di 12:23
Léf. 17:11Le 8:15; 16:18
Léf. 17:11Mt 26:28; Ro 3:25; 5:9; Ef 1:7; Heb 9:22; 13:12; 1Pe 1:2; 1Jo 1:7; Ifi 1:5
Léf. 17:12Ẹk 12:49
Léf. 17:12Di 12:23
Léf. 17:13Di 12:16; 15:23
Léf. 17:14Le 17:10, 11
Léf. 17:15Ẹk 22:31; Di 14:21
Léf. 17:15Le 11:40
Léf. 17:16Nọ 19:20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 17:1-16

Léfítíkù

17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí:

3 “‘“Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì bá pa akọ màlúù tàbí ọmọ àgbò tàbí ewúrẹ́ nínú ibùdó tàbí tó pa á ní ẹ̀yìn ibùdó, 4 dípò kó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà níwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, ọkùnrin náà máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ṣe ni kí ẹ pa á, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 5 Èyí máa mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ẹbọ wọn, tí wọ́n ń rú nínú pápá gbalasa wá fún Jèhófà, sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, sọ́dọ̀ àlùfáà. Kí wọ́n fi nǹkan wọ̀nyí rúbọ bí ẹbọ ìrẹ́pọ̀ sí Jèhófà.+ 6 Kí àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sórí pẹpẹ Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì mú kí ọ̀rá ẹran náà rú èéfín sí Jèhófà láti mú òórùn dídùn* jáde.+ 7 Torí náà, kí wọ́n má ṣe rú ẹbọ mọ́ sí àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́,*+ èyí tí wọ́n ń bá ṣèṣekúṣe.+ Kí èyí jẹ́ àṣẹ tó máa wà títí lọ fún yín, jálẹ̀ àwọn ìran yín.”’

8 “Kí o sọ fún wọn pé, ‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá rú ẹbọ sísun tàbí tó rúbọ, 9 tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rúbọ sí Jèhófà, kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+

10 “‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, ó dájú pé mi ò ní fi ojú rere wo ẹni* tó ń jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 11 Torí inú ẹ̀jẹ̀+ ni ẹ̀mí* ẹran wà, èmi fúnra mi sì ti fi sórí pẹpẹ+ fún yín kí ẹ lè ṣe ètùtù fún ara yín,* torí ẹ̀jẹ̀ ló ń ṣe ètùtù+ nípasẹ̀ ẹ̀mí* tó wà nínú rẹ̀. 12 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìkankan* nínú yín ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín+ ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.”+

13 “‘Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé láàárín yín bá ń ṣọdẹ, tó sì mú ẹran ìgbẹ́ tàbí ẹyẹ tí ẹ lè jẹ, ó gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde,+ kó sì fi erùpẹ̀ bò ó. 14 Torí ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí* gbogbo onírúurú ẹran, torí pé ẹ̀mí* wà nínú ẹ̀jẹ̀ náà. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran èyíkéyìí, torí ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí* gbogbo onírúurú ẹran. Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹ́.”+ 15 Tí ẹnikẹ́ni* bá jẹ òkú ẹran tàbí èyí tí ẹran inú igbó fà ya,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì ló jẹ ẹ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì di aláìmọ́ títí di alẹ́;+ lẹ́yìn náà, á di mímọ́. 16 Àmọ́ tí kò bá fọ̀ wọ́n, tí kò sì wẹ̀,* yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́