ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 26:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 torí èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’ mi,+ tí a máa dà jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn,+ kí wọ́n lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+

  • Róòmù 3:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ọlọ́run fi í lélẹ̀ láti jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ Kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn, torí Ọlọ́run, nínú ìmúmọ́ra* rẹ̀, ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé nígbà àtijọ́ jini.

  • Róòmù 5:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Nígbà tí a sì ti wá pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ó dájú pé ó máa mú kí a bọ́ lọ́wọ́ ìrunú.+

  • Éfésù 1:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ipasẹ̀ ìràpadà tó fi ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ san ni a fi rí ìtúsílẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa,+ nítorí ọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.

  • Hébérù 9:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Àní bí Òfin ṣe sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́,+ ìdáríjì kankan ò sì lè wáyé àfi tí a bá tú ẹ̀jẹ̀ jáde.+

  • Hébérù 13:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Torí náà, Jésù náà jìyà lẹ́yìn odi* ìlú+ kó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn èèyàn di mímọ́.+

  • 1 Pétérù 1:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọ́run tó jẹ́ Baba ti mọ̀ tẹ́lẹ̀,+ tí ẹ̀mí sọ di mímọ́,+ kí ẹ lè ṣègbọràn, kí a sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi sí yín lára:+

      Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà yín máa pọ̀ sí i.

  • 1 Jòhánù 1:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Àmọ́, tí a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe wà nínú ìmọ́lẹ̀, a ní àjọṣe pẹ̀lú ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.+

  • Ìfihàn 1:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 àti látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, “Ẹlẹ́rìí Olóòótọ́,”+ “àkọ́bí nínú àwọn òkú,”+ àti “Alákòóso àwọn ọba ayé.”+

      Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa,+ tó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa+—

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́