ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kíróníkà

      • Ikú Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ (1-14)

1 Kíróníkà 10:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:1-5; 2Sa 1:21, 25

1 Kíróníkà 10:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 8:33

1 Kíróníkà 10:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:9, 10

1 Kíróníkà 10:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìkọlà.”

  • *

    Tàbí “ṣe mí ṣúkaṣùka.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 16:21, 23
  • +1Kr 10:13

1 Kíróníkà 10:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:6, 7

1 Kíróníkà 10:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

1 Kíróníkà 10:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 28:4; 31:8-10

1 Kíróníkà 10:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 16:23, 24

1 Kíróníkà 10:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 5:2

1 Kíróníkà 10:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 11:1
  • +1Sa 31:11-13

1 Kíróníkà 10:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 2:5; 21:12

1 Kíróníkà 10:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 13:13; 15:22, 23
  • +Le 20:6; 1Sa 28:7

1 Kíróníkà 10:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Rut 4:17; 1Sa 13:14; 15:27, 28; 2Sa 5:3

Àwọn míì

1 Kíró. 10:11Sa 31:1-5; 2Sa 1:21, 25
1 Kíró. 10:21Kr 8:33
1 Kíró. 10:31Sa 26:9, 10
1 Kíró. 10:4Ond 16:21, 23
1 Kíró. 10:41Kr 10:13
1 Kíró. 10:61Sa 31:6, 7
1 Kíró. 10:81Sa 28:4; 31:8-10
1 Kíró. 10:9Ond 16:23, 24
1 Kíró. 10:101Sa 5:2
1 Kíró. 10:111Sa 11:1
1 Kíró. 10:111Sa 31:11-13
1 Kíró. 10:122Sa 2:5; 21:12
1 Kíró. 10:131Sa 13:13; 15:22, 23
1 Kíró. 10:13Le 20:6; 1Sa 28:7
1 Kíró. 10:14Rut 4:17; 1Sa 13:14; 15:27, 28; 2Sa 5:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kíróníkà 10:1-14

Kíróníkà Kìíní

10 Nígbà náà, àwọn Filísínì ń bá Ísírẹ́lì jà. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá kúrò níwájú àwọn Filísínì, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú sórí Òkè Gíbóà.+ 2 Àwọn Filísínì sún mọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn Filísínì sì pa Jónátánì, Ábínádábù àti Maliki-ṣúà,+ àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù. 3 Ìjà náà le mọ́ Sọ́ọ̀lù, ọwọ́ àwọn tafàtafà+ bà á, wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára. 4 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́* yìí má bàa wá hùwà ìkà+ sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+ 5 Nígbà tí ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra rí i pé Sọ́ọ̀lù ti kú, òun náà ṣubú lé idà tirẹ̀, ó sì kú. 6 Bí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe kú nìyẹn, tí gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ sì kú pa pọ̀.+ 7 Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó wà ní àfonífojì* rí i pé gbogbo èèyàn ti sá lọ àti pé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ; lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì wá, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

8 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filísínì wá bọ́ àwọn nǹkan tó wà lára àwọn tí wọ́n pa, wọ́n rí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti kú sórí Òkè Gíbóà.+ 9 Wọ́n bọ́ àwọn nǹkan tó wà lára rẹ̀, wọ́n gé orí rẹ̀ kúrò, wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì pé kí wọ́n ròyìn rẹ̀ fún àwọn òrìṣà+ wọn àti àwọn èèyàn wọn. 10 Wọ́n wá gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sínú ilé* ọlọ́run wọn, wọ́n sì kan agbárí rẹ̀ mọ́ ilé Dágónì.+

11 Nígbà tí gbogbo àwọn ará Jábéṣì+ ní Gílíádì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù,+ 12 gbogbo àwọn jagunjagun gbéra, wọ́n sì gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti òkú àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé wọn wá sí Jábéṣì, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi ńlá ní Jábéṣì,+ wọ́n sì fi ọjọ́ méje gbààwẹ̀.

13 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe kú nìyẹn nítorí ìwà àìṣòótọ́ tó hù sí Jèhófà torí pé kò ṣe ohun tí Jèhófà+ sọ àti pé ó lọ wádìí lọ́dọ̀ abẹ́mìílò+ 14 dípò kó wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà. Torí náà, Ó pa á, ó sì gbé ìjọba náà fún Dáfídì ọmọ Jésè.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́