ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 28
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Jeremáyà àti Hananáyà tó jẹ́ wòlíì èké (1-17)

Jeremáyà 28:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:17; 2Kr 36:10
  • +Joṣ 11:19; 2Sa 21:2

Jeremáyà 28:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:4, 8

Jeremáyà 28:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọdún tó jẹ́ ọjọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:11, 13; Jer 27:16; Da 1:2

Jeremáyà 28:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:8; 25:27; Jer 37:1
  • +2Ọb 23:36; 24:6
  • +2Ọb 24:12, 14; Jer 24:1

Jeremáyà 28:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Kó rí bẹ́ẹ̀.”

Jeremáyà 28:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àìsàn.”

Jeremáyà 28:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:2

Jeremáyà 28:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 28:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 187-188

Jeremáyà 28:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:2

Jeremáyà 28:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:48; Jer 5:19
  • +Jer 27:6; Da 2:37, 38

Jeremáyà 28:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 28:1
  • +Jer 14:14; 23:21; 27:15; Isk 13:3

Jeremáyà 28:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 13:5; 18:20; Jer 29:32

Àwọn míì

Jer. 28:12Ọb 24:17; 2Kr 36:10
Jer. 28:1Joṣ 11:19; 2Sa 21:2
Jer. 28:2Jer 27:4, 8
Jer. 28:32Ọb 24:11, 13; Jer 27:16; Da 1:2
Jer. 28:42Ọb 24:8; 25:27; Jer 37:1
Jer. 28:42Ọb 23:36; 24:6
Jer. 28:42Ọb 24:12, 14; Jer 24:1
Jer. 28:10Jer 27:2
Jer. 28:11Jer 28:4
Jer. 28:13Jer 27:2
Jer. 28:14Di 28:48; Jer 5:19
Jer. 28:14Jer 27:6; Da 2:37, 38
Jer. 28:15Jer 28:1
Jer. 28:15Jer 14:14; 23:21; 27:15; Isk 13:3
Jer. 28:16Di 13:5; 18:20; Jer 29:32
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 28:1-17

Jeremáyà

28 Ní ọdún yẹn kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà+ ọba Júdà, ní ọdún kẹrin, ní oṣù karùn-ún, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì láti Gíbíónì+ sọ fún mi ní ilé Jèhófà lójú àwọn àlùfáà àti lójú gbogbo àwọn èèyàn náà pé: 2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Màá ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.+ 3 Kí ọdún* méjì tó pé, gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó láti ibí yìí lọ sí Bábílónì ni màá kó pa dà wá sí ibí yìí.’”+ 4 “‘Màá sì mú Jekonáyà+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà àti gbogbo ará Júdà tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì+ pa dà wá sí ibí yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘nítorí màá ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.’”

5 Ìgbà náà ni wòlíì Jeremáyà bá wòlíì Hananáyà sọ̀rọ̀ lójú àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn tó dúró ní ilé Jèhófà. 6 Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Àmín!* Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Jèhófà mú ọ̀rọ̀ rẹ ṣẹ pé kí àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà àti gbogbo àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì pa dà wá sí ibí yìí! 7 Síbẹ̀, jọ̀wọ́, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ létí rẹ àti létí gbogbo èèyàn. 8 Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn wòlíì tó wà ṣáájú mi àti ṣáájú rẹ ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀ ilẹ̀ àti àwọn ìjọba ńlá, nípa ogun, àjálù àti àjàkálẹ̀ àrùn.* 9 Tí wòlíì kan bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlàáfíà, tí ọ̀rọ̀ wòlíì náà sì ṣẹ, ìgbà náà la máa mọ̀ pé Jèhófà ló rán wòlíì náà lóòótọ́.”

10 Ni wòlíì Hananáyà bá mú ọ̀pá àjàgà tó wà lọ́rùn wòlíì Jeremáyà kúrò, ó sì ṣẹ́ ẹ.+ 11 Hananáyà sì sọ lójú gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí màá ṣe ṣẹ́ àjàgà Nebukadinésárì ọba Bábílónì kúrò ní ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè nìyí kí ọdún méjì tó pé.’”+ Wòlíì Jeremáyà sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

12 Lẹ́yìn tí wòlíì Hananáyà ti ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà tó mú kúrò lọ́rùn wòlíì Jeremáyà, Jèhófà wá sọ fún Jeremáyà pé: 13 “Lọ sọ fún Hananáyà pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ti ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà igi,+ àmọ́ dípò rẹ̀, ọ̀pá àjàgà irin lo máa ṣe.” 14 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Màá fi ọ̀pá àjàgà irin sí ọrùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, láti sin Nebukadinésárì ọba Bábílónì, wọ́n sì gbọ́dọ̀ sìn ín.+ Kódà màá fún un ní àwọn ẹran inú igbó.”’”+

15 Wòlíì Jeremáyà wá sọ fún wòlíì Hananáyà+ pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ Hananáyà! Jèhófà kò rán ọ, àmọ́ o ti mú kí àwọn èèyàn yìí gbẹ́kẹ̀ lé irọ́.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó! Màá mú ọ kúrò lórí ilẹ̀. Ọdún yìí ni wàá kú, nítorí o ti mú kí àwọn èèyàn dìtẹ̀ sí Jèhófà.’”+

17 Torí náà, wòlíì Hananáyà kú ní ọdún yẹn, ní oṣù keje.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́