ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 36
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Senakérúbù gbéjà ko Júdà (1-3)

      • Rábúṣákè pẹ̀gàn Jèhófà (4-22)

Àìsáyà 36:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 10:5
  • +2Ọb 18:13; 2Kr 32:1; Ais 8:7, 8; 10:28-32; 33:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 383-385

Àìsáyà 36:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “olórí agbọ́tí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:9
  • +2Ọb 19:8
  • +Ais 7:3
  • +2Ọb 18:17, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 386

Àìsáyà 36:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 22:20, 21
  • +2Ọb 19:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2007, ojú ìwé 9

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 386

Àìsáyà 36:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:19-25; 19:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 386

Àìsáyà 36:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:1, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 386

Àìsáyà 36:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, koríko etí omi.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:4; Ais 30:2, 7; Jer 37:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 386

Àìsáyà 36:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:1, 4; 2Kr 31:1
  • +Di 12:11; 2Kr 7:12; 32:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 386

Àìsáyà 36:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 387

Àìsáyà 36:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 387

Àìsáyà 36:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Síríà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 22:15
  • +2Ọb 18:17
  • +Ẹsr 4:7; Da 2:4
  • +2Ọb 18:26, 27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 387-388

Àìsáyà 36:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 387-388

Àìsáyà 36:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:18
  • +2Ọb 18:28-35

Àìsáyà 36:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:11, 15; Da 3:15

Àìsáyà 36:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:22

Àìsáyà 36:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ wá ìbùkún lọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì jáde wá bá mi.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 387-388

Àìsáyà 36:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:6, 22, 23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 387-388

Àìsáyà 36:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:11, 12; 2Kr 32:14; Ais 37:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 388

Àìsáyà 36:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:23
  • +2Ọb 17:24
  • +2Ọb 17:6, 22, 23; Ais 10:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 388-389

Àìsáyà 36:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:17, 18; 2Kr 32:15; Ais 37:23

Àìsáyà 36:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:36, 37; Owe 9:7

Àìsáyà 36:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 22:15

Àwọn míì

Àìsá. 36:1Ais 10:5
Àìsá. 36:12Ọb 18:13; 2Kr 32:1; Ais 8:7, 8; 10:28-32; 33:8
Àìsá. 36:22Kr 32:9
Àìsá. 36:22Ọb 19:8
Àìsá. 36:2Ais 7:3
Àìsá. 36:22Ọb 18:17, 18
Àìsá. 36:3Ais 22:20, 21
Àìsá. 36:32Ọb 19:2
Àìsá. 36:42Ọb 18:19-25; 19:10
Àìsá. 36:52Ọb 18:1, 7
Àìsá. 36:62Ọb 17:4; Ais 30:2, 7; Jer 37:7
Àìsá. 36:72Ọb 18:1, 4; 2Kr 31:1
Àìsá. 36:7Di 12:11; 2Kr 7:12; 32:12
Àìsá. 36:82Ọb 18:13
Àìsá. 36:11Ais 22:15
Àìsá. 36:112Ọb 18:17
Àìsá. 36:11Ẹsr 4:7; Da 2:4
Àìsá. 36:112Ọb 18:26, 27
Àìsá. 36:132Kr 32:18
Àìsá. 36:132Ọb 18:28-35
Àìsá. 36:142Kr 32:11, 15; Da 3:15
Àìsá. 36:152Ọb 19:22
Àìsá. 36:172Ọb 17:6, 22, 23
Àìsá. 36:182Ọb 19:11, 12; 2Kr 32:14; Ais 37:11, 12
Àìsá. 36:19Jer 49:23
Àìsá. 36:192Ọb 17:24
Àìsá. 36:192Ọb 17:6, 22, 23; Ais 10:11
Àìsá. 36:202Ọb 19:17, 18; 2Kr 32:15; Ais 37:23
Àìsá. 36:212Ọb 18:36, 37; Owe 9:7
Àìsá. 36:22Ais 22:15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 36:1-22

Àìsáyà

36 Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+ 2 Ọba Ásíríà wá rán Rábúṣákè*+ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì+ sí Ọba Hẹsikáyà ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n dúró síbi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà,+ èyí tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀.+ 3 Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣébínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí sì jáde wá bá a.

4 Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+ 5 Ò ń sọ pé, ‘Mo ní ọgbọ́n àti agbára láti jagun,’ àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán nìyẹn. Ta lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi gbójúgbóyà ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+ 6 Wò ó! Ṣé Íjíbítì tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e.+ 7 Tí ẹ bá sì sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni a gbẹ́kẹ̀ lé,’ ṣé òun kọ́ ni Hẹsikáyà mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò,+ tó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ yìí ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀’?”’+ 8 Ní báyìí, ẹ wò ó, olúwa mi ọba Ásíríà+ pè yín níjà: Ẹ jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin, ká wá wò ó bóyá ẹ máa lè rí àwọn agẹṣin tó máa gùn wọ́n. 9 Báwo wá ni ẹ ṣe lè borí gómìnà kan ṣoṣo tó kéré jù lára àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, nígbà tó jẹ́ pé Íjíbítì lẹ gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa fún yín ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin? 10 Ṣé láìgba àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo wá gbéjà ko ilẹ̀ yìí láti pa á run ni? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún mi pé, ‘Lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì pa á run.’”

11 Ni Élíákímù àti Ṣébínà+ pẹ̀lú Jóà bá sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀ọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì*+ torí a gbọ́ èdè náà; má fi èdè àwọn Júù bá wa sọ̀rọ̀ lójú àwọn èèyàn tó wà lórí ògiri.”+ 12 Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin àti olúwa yín nìkan ni olúwa mi ní kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ni? Ṣé kò tún rán mi sí àwọn ọkùnrin tó ń jókòó lórí ògiri, àwọn tó máa jẹ ìgbẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì máa mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”

13 Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀,+ ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 14 Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín sílẹ̀.+ 15 Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+ bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.” 16 Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 17 títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà?+ 19 Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì àti ti Áápádì+ wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù+ wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 20 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ yìí ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+

21 Àmọ́ wọ́n dákẹ́, wọn ò fún un lésì kankan, nítorí àṣẹ ọba ni pé, “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 22 Ṣùgbọ́n Élíákímù ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣébínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí wá sọ́dọ̀ Hẹsikáyà, pẹ̀lú ẹ̀wù yíya lọ́rùn wọn, wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́