ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Wọ́n gbé Ìsíkíẹ́lì lọ sí Jerúsálẹ́mù nínú ìran (1-4)

      • Ó rí àwọn ohun ìríra nínú tẹ́ńpìlì (5-18)

        • Àwọn obìnrin ń sunkún torí Támúsì (14)

        • Àwọn ọkùnrin ń forí balẹ̀ fún oòrùn (16)

Ìsíkíẹ́lì 8:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2018, ojú ìwé 3

Ìsíkíẹ́lì 8:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:9
  • +Isk 1:4, 27

Ìsíkíẹ́lì 8:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àmì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 20:2; Isk 9:2
  • +Di 32:16

Ìsíkíẹ́lì 8:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:34
  • +Isk 1:27, 28

Ìsíkíẹ́lì 8:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àmì.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 53-54, 56

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1993, ojú ìwé 27

Ìsíkíẹ́lì 8:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:14
  • +Jer 26:4, 6

Ìsíkíẹ́lì 8:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:10
  • +Ẹk 20:4, 5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1993, ojú ìwé 27

Ìsíkíẹ́lì 8:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:3, 4; 25:22; Jer 26:24
  • +Isk 16:17, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 54-58

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1993, ojú ìwé 27

Ìsíkíẹ́lì 8:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí ó to.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 29:15; Isk 9:9

Ìsíkíẹ́lì 8:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 57-58

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1993, ojú ìwé 27-28

Ìsíkíẹ́lì 8:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:14

Ìsíkíẹ́lì 8:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 4:9
  • +Di 4:19; 2Ọb 17:16; Jer 8:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 57, 58-59

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1993, ojú ìwé 28

Ìsíkíẹ́lì 8:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó jọ pé ẹ̀ka tí wọ́n fi ń bọ̀rìṣà ni.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:16; Jer 19:4; Isk 9:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1993, ojú ìwé 28

Ìsíkíẹ́lì 8:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 5:11; 7:9
  • +Ais 1:15; Mik 3:4

Àwọn míì

Ìsík. 8:2Da 7:9
Ìsík. 8:2Isk 1:4, 27
Ìsík. 8:3Jer 20:2; Isk 9:2
Ìsík. 8:3Di 32:16
Ìsík. 8:4Ẹk 40:34
Ìsík. 8:4Isk 1:27, 28
Ìsík. 8:62Kr 36:14
Ìsík. 8:6Jer 26:4, 6
Ìsík. 8:10Le 11:10
Ìsík. 8:10Ẹk 20:4, 5
Ìsík. 8:112Ọb 22:3, 4; 25:22; Jer 26:24
Ìsík. 8:11Isk 16:17, 18
Ìsík. 8:12Ais 29:15; Isk 9:9
Ìsík. 8:152Kr 36:14
Ìsík. 8:162Kr 4:9
Ìsík. 8:16Di 4:19; 2Ọb 17:16; Jer 8:1, 2
Ìsík. 8:172Ọb 21:16; Jer 19:4; Isk 9:9
Ìsík. 8:18Isk 5:11; 7:9
Ìsík. 8:18Ais 1:15; Mik 3:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 8:1-18

Ìsíkíẹ́lì

8 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà, ọdún kẹfà, nígbà tí mo jókòó sínú ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Júdà sì jókòó síwájú mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fún mi lágbára níbẹ̀. 2 Bí mo ṣe ń wò, mo rí ẹnì kan tó rí bí iná; ó jọ pé iná wà níbi ìbàdí rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀.+ Láti ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó mọ́lẹ̀, ó rí bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà tó ń dán yanran.+ 3 Ó wá na ohun tó dà bí ọwọ́ jáde, ó fa irun orí mi, ẹ̀mí kan sì gbé mi nínú ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lọ sí agbedeméjì ayé àti ọ̀run. Ó gbé mi wá sí Jerúsálẹ́mù, sí ẹnubodè inú,+ èyí tó kọjú sí àríwá, níbi tí ère* owú tó ń múni jowú wà.+ 4 Wò ó! ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀,+ ó dà bí ohun tí mo rí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.+

5 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jọ̀ọ́ gbójú sókè kí o wo àríwá.” Torí náà, mo wo àríwá, mo sì rí ère* owú náà ní àríwá ẹnubodè pẹpẹ. 6 Ó sì sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun ìríra tó burú jáì tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe níbí,+ tó mú kí n jìnnà sí ibi mímọ́ mi?+ O máa rí àwọn ohun tó ń ríni lára tó tún burú ju èyí lọ.”

7 Ó wá mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá, nígbà tí mo sì wo ibẹ̀, mo rí ihò kan lára ògiri. 8 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jọ̀ọ́ dá ògiri náà lu.” Ni mo bá dá ògiri náà lu, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan. 9 Ó sọ fún mi pé: “Wọlé, kí o lè rí iṣẹ́ ibi tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe níbí.” 10 Torí náà, mo wọlé, mo wò ó, mo sì rí oríṣiríṣi àwòrán ohun tó ń rákò àti ẹranko tó ń kóni nírìíra+ àti gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin* ilé Ísírẹ́lì;+ wọ́n gbẹ́ ẹ sí ara ògiri káàkiri. 11 Àádọ́rin (70) ọkùnrin lára àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì dúró níwájú wọn, Jasanáyà ọmọ Ṣáfánì+ sì wà lára wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú àwo tùràrí rẹ̀ dání, èéfín tùràrí tó ní òórùn dídùn sì ń gòkè lọ.+ 12 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, kálukú nínú yàrá inú tó kó* àwọn ère rẹ̀ sí? Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ò rí wa. Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀.’”+

13 Ó wá sọ fún mi pé: “Wàá rí àwọn ohun tó ń ríni lára tí wọ́n ń ṣe tó tún burú ju èyí lọ.” 14 Torí náà, ó mú mi wá sí ẹnubodè àríwá ní ilé Jèhófà, mo sì rí àwọn obìnrin tí wọ́n jókòó síbẹ̀, tí wọ́n ń sunkún torí ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Támúsì.

15 Ó sọ fún mi síwájú sí i pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé ìwọ náà rí i? Wàá rí àwọn ohun ìríra tó tún burú ju èyí lọ.”+ 16 Torí náà, ó mú mi wá sí àgbàlá inú ní ilé Jèhófà.+ Ní ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì Jèhófà, láàárín ibi àbáwọlé* àti pẹpẹ, nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) wà níbẹ̀ tí wọ́n kẹ̀yìn sí tẹ́ńpìlì Jèhófà, tí wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn; wọ́n ń forí balẹ̀ fún oòrùn níbẹ̀.+

17 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé ìwọ náà rí i? Ṣé ohun tí kò tó nǹkan ni lójú ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, tí wọ́n ń hu ìwà ipá ní gbogbo ilẹ̀ náà,+ tí wọ́n sì ń ṣẹ̀ mí? Wọ́n ń na ẹ̀ka* sí mi ní imú. 18 Torí náà, màá bínú sí wọn. Mi ò ní ṣàánú wọn, mi ò sì ní yọ́nú sí wọn.+ Bí wọ́n bá tiẹ̀ kígbe tantan kí n lè gbọ́, mi ò ní dá wọn lóhùn.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́