Òwe
4 Sọ fún ọgbọ́n pé, “Arábìnrin mi ni ọ́,”
Kí o sì pe òye ní “ìbátan mi,”
Mo bojú wolẹ̀ látojú fèrèsé,*
7 Bí mo ṣe ń wo àwọn aláìmọ̀kan,*
Mo kíyè sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò ní làákàyè* láàárín àwọn ọ̀dọ́.+
8 Ó gba ojú ọ̀nà tó wà nítòsí ìyànà ilé obìnrin náà kọjá,
Ó sì rìn lọ sí ọ̀nà ilé obìnrin náà
Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú, tí òkùnkùn sì ń kùn.
11 Ó jẹ́ aláriwo àti aláfojúdi.+
Kì í* dúró sílé.
13 Obìnrin náà gbá a mú, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu;
Ó fi ọ̀dájú sọ fún un pé:
14 “Mo ti rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+
Òní ni mo san àwọn ẹ̀jẹ́ mi.
15 Ìdí nìyẹn tí mo fi jáde wá pàdé rẹ,
Láti wá ọ, mo sì ti rí ọ!
17 Mo ti fi òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn mi.+
18 Wá, jẹ́ ká jọ ṣeré ìfẹ́ títí di àárọ̀;
Jẹ́ ká gbádùn ìfẹ́ láàárín ara wa,
19 Nítorí ọkọ mi ò sí nílé;
Ó ti rin ìrìn àjò lọ sí ọ̀nà jíjìn.
20 Ó gbé àpò owó dání,
Kò sì ní pa dà títí di ọjọ́ òṣùpá àrànmọ́jú.”
21 Ó fi ọ̀rọ̀ tó ń yíni lérò pa dà ṣì í lọ́nà.+
Ó fi ọ̀rọ̀ dídùn fa ojú rẹ̀ mọ́ra.
22 Lójijì, ó tẹ̀ lé obìnrin náà, bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,
Bí òmùgọ̀ tí wọ́n fẹ́ fìyà jẹ nínú àbà,*+
23 Títí ọfà fi gún ẹ̀dọ̀ rẹ̀ ní àgúnyọ;
Bí ẹyẹ tó kó sínú pańpẹ́, kò mọ̀ pé ẹ̀mí òun máa lọ sí i.+
24 Ní báyìí, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ mi;
Ẹ fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ.
25 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀.
Má rìn gbéregbère wọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀,+
26 Nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣekú pa,+
Àwọn tó ti pa sì pọ̀ gan-an.+
27 Ilé rẹ̀ lọ sí Isà Òkú;*
Ó sọ̀ kalẹ̀ sínú yàrá ikú.