ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Orin Sólómọ́nì 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Orin Sólómọ́nì

    • Ọ̀DỌ́BÌNRIN ṢÚLÁMÁÍTÌ WÀ NÍ JERÚSÁLẸ́MÙ (3:6–8:4)

Orin Sólómọ́nì 6:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 1:7; 2:16

Orin Sólómọ́nì 6:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 7:10
  • +Sol 2:16

Orin Sólómọ́nì 6:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ìlú Tó Wuni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 1:9
  • +1Ọb 14:17; 15:33
  • +Sm 48:2
  • +Sol 6:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 20

Orin Sólómọ́nì 6:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 1:15; 4:9; 7:4
  • +Sol 4:1-3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 19

Orin Sólómọ́nì 6:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀bátí.”

Orin Sólómọ́nì 6:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2011, ojú ìwé 11

Orin Sólómọ́nì 6:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹni mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 2:14

Orin Sólómọ́nì 6:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tó ń sọ̀ kalẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 6:4

Orin Sólómọ́nì 6:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yọ ìtànná.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 2:5

Orin Sólómọ́nì 6:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn mi.”

  • *

    Tàbí “tó fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn.”

Orin Sólómọ́nì 6:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ijó Máhánáímù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 1:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 20

Àwọn míì

Orin Sól. 6:2Sol 1:7; 2:16
Orin Sól. 6:3Sol 7:10
Orin Sól. 6:3Sol 2:16
Orin Sól. 6:4Sol 1:9
Orin Sól. 6:41Ọb 14:17; 15:33
Orin Sól. 6:4Sm 48:2
Orin Sól. 6:4Sol 6:10
Orin Sól. 6:5Sol 1:15; 4:9; 7:4
Orin Sól. 6:5Sol 4:1-3
Orin Sól. 6:81Ọb 11:1
Orin Sól. 6:9Sol 2:14
Orin Sól. 6:10Sol 6:4
Orin Sól. 6:11Onw 2:5
Orin Sól. 6:13Sol 1:6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Orin Sólómọ́nì 6:1-13

Orin Sólómọ́nì

6 “Ibo ni olólùfẹ́ rẹ lọ,

Ìwọ tó rẹwà jù nínú àwọn obìnrin?

Ibo ni olólùfẹ́ rẹ gbà?

Jẹ́ ká jọ wá a lọ.”

 2 “Olólùfẹ́ mi ti lọ sí ọgbà rẹ̀,

Síbi ebè tí wọ́n gbin àwọn ewé tó ń ta sánsán sí,

Kó lè tọ́jú àwọn àgùntàn nínú ọgbà,

Kó sì já àwọn òdòdó lílì.+

 3 Olólùfẹ́ mi ló ni mí,

Èmi ni mo sì ni olólùfẹ́ mi.+

Ó ń tọ́jú àwọn àgùntàn láàárín àwọn òdòdó lílì.”+

 4 “Olólùfẹ́ mi,+ o rẹwà bíi Tírísà,*+

O wuni bíi Jerúsálẹ́mù,+

O gbayì gan-an bí àwọn ọmọ ogun tó yí ọ̀págun wọn ká.+

 5 Yí ojú rẹ+ kúrò lọ́dọ̀ mi,

Torí ara mi ò gbà á.

Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́

Tó ń rọ́ bọ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Gílíádì.+

 6 Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn,

Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,

Gbogbo wọn bí ìbejì,

Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.

 7 Àwọn ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétì

Lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.

 8 Ọgọ́ta (60) ayaba lè wà,

Ọgọ́rin (80) wáhàrì* lè wà,

Ọ̀dọ́bìnrin sì lè pọ̀ láìníye.+

 9 Àmọ́ ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi,+ onítèmi tí ẹwà rẹ̀ ò lábùlà.

Ọ̀kan ṣoṣo tí ìyá rẹ̀ ní.

Òun ni ààyò* ẹni tó bí i.

Àwọn ọmọbìnrin rí i, wọ́n sì ń pè é ní aláyọ̀;

Àwọn ayaba àti wáhàrì rí i, wọ́n sì ń yìn ín.

10 ‘Ta ni obìnrin yìí tó ń tàn* bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,

Tó lẹ́wà bí òṣùpá àrànmọ́jú,

Tó mọ́ rekete bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn,

Tó gbayì gan-an bí àwọn ọmọ ogun tó yí ọ̀págun wọn ká?’”+

11 “Mo lọ sínú ọgbà igi eléso,+

Kí n lè rí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù ní àfonífojì,

Kí n lè rí i bóyá àjàrà ti hù,*

Bóyá àwọn igi pómégíránétì ti yọ òdòdó.

12 Kí n tó mọ̀,

Ohun tó wù mí* ti mú kí n dé

Ibi tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn èèyàn mi pàtàkì* wà.”

13 “Pa dà wá, pa dà wá, Ṣúlámáítì!

Pa dà wá, pa dà wá,

Ká lè máa wò ẹ́!”

“Kí ló dé tí ẹ̀ ń wo Ṣúlámáítì?”+

“Ó dà bí ijó àwùjọ méjì!”*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́