ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Wọ́n bí Ísákì (1-7)

      • Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́ (8, 9)

      • Ó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ (10-21)

      • Ábúráhámù bá Ábímélékì dá májẹ̀mú (22-34)

Jẹ́nẹ́sísì 21:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:10

Jẹ́nẹ́sísì 21:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:11
  • +Jẹ 17:21; 18:10, 14; Ro 9:9

Jẹ́nẹ́sísì 21:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:19; Joṣ 24:3; Ro 9:7

Jẹ́nẹ́sísì 21:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:12; Le 12:3; Iṣe 7:8

Jẹ́nẹ́sísì 21:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “á fi mí rẹ́rìn-ín.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 14-15

Jẹ́nẹ́sísì 21:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 103

Jẹ́nẹ́sísì 21:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:4, 15
  • +Jẹ 15:13; Ga 4:22, 29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 26

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 103

Jẹ́nẹ́sísì 21:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:2, 4; Ga 4:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Yiyan, ojú ìwé 83

Jẹ́nẹ́sísì 21:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 15

Jẹ́nẹ́sísì 21:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ohùn rẹ̀.”

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:19; Ro 9:7; Heb 11:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2006, ojú ìwé 6-7

Jẹ́nẹ́sísì 21:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 4:22
  • +Jẹ 16:9, 10; 17:20; 25:12, 16

Jẹ́nẹ́sísì 21:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:5, 6
  • +Jẹ 22:19

Jẹ́nẹ́sísì 21:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:11
  • +Jẹ 16:7, 8

Jẹ́nẹ́sísì 21:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 1:29-31

Jẹ́nẹ́sísì 21:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:16

Jẹ́nẹ́sísì 21:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 10:12

Jẹ́nẹ́sísì 21:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:17, 18; 26:26, 28

Jẹ́nẹ́sísì 21:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:14, 15

Jẹ́nẹ́sísì 21:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 26:15, 20

Jẹ́nẹ́sísì 21:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Kànga Ìbúra tàbí Kànga Ohun Méje.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 26:32, 33

Jẹ́nẹ́sísì 21:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 26:26, 28
  • +Jẹ 10:13, 14; 26:1

Jẹ́nẹ́sísì 21:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:8, 9; 26:25
  • +Sm 90:2; Ais 40:28; 1Ti 1:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé,

    2/2020, ojú ìwé 5-6

Jẹ́nẹ́sísì 21:34

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì bí àjèjì.”

  • *

    Ní Héb., “ó lo ọjọ́ tó pọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:8, 9

Àwọn míì

Jẹ́n. 21:1Jẹ 18:10
Jẹ́n. 21:2Heb 11:11
Jẹ́n. 21:2Jẹ 17:21; 18:10, 14; Ro 9:9
Jẹ́n. 21:3Jẹ 17:19; Joṣ 24:3; Ro 9:7
Jẹ́n. 21:4Jẹ 17:12; Le 12:3; Iṣe 7:8
Jẹ́n. 21:9Jẹ 16:4, 15
Jẹ́n. 21:9Jẹ 15:13; Ga 4:22, 29
Jẹ́n. 21:10Jẹ 15:2, 4; Ga 4:30
Jẹ́n. 21:11Jẹ 17:18
Jẹ́n. 21:12Jẹ 17:19; Ro 9:7; Heb 11:18
Jẹ́n. 21:13Ga 4:22
Jẹ́n. 21:13Jẹ 16:9, 10; 17:20; 25:12, 16
Jẹ́n. 21:14Jẹ 25:5, 6
Jẹ́n. 21:14Jẹ 22:19
Jẹ́n. 21:17Jẹ 16:11
Jẹ́n. 21:17Jẹ 16:7, 8
Jẹ́n. 21:181Kr 1:29-31
Jẹ́n. 21:20Jẹ 16:16
Jẹ́n. 21:21Nọ 10:12
Jẹ́n. 21:22Jẹ 20:17, 18; 26:26, 28
Jẹ́n. 21:23Jẹ 20:14, 15
Jẹ́n. 21:25Jẹ 26:15, 20
Jẹ́n. 21:31Jẹ 26:32, 33
Jẹ́n. 21:32Jẹ 26:26, 28
Jẹ́n. 21:32Jẹ 10:13, 14; 26:1
Jẹ́n. 21:33Jẹ 12:8, 9; 26:25
Jẹ́n. 21:33Sm 90:2; Ais 40:28; 1Ti 1:17
Jẹ́n. 21:34Heb 11:8, 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 21:1-34

Jẹ́nẹ́sísì

21 Jèhófà rántí Sérà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, Jèhófà sì ṣe ohun tó ṣèlérí+ fún Sérà. 2 Sérà lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní àkókò tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un.+ 3 Ábúráhámù pe orúkọ ọmọ tuntun tí Sérà bí fún un ní Ísákì.+ 4 Ábúráhámù sì dádọ̀dọ́* Ísákì ọmọ rẹ̀ nígbà tó pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ fún un.+ 5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tó bí Ísákì ọmọ rẹ̀. 6 Sérà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín; gbogbo ẹni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀ á bá mi rẹ́rìn-ín.”* 7 Ó fi kún un pé: “Ta ni ì bá sọ fún Ábúráhámù pé, ‘Ó dájú pé Sérà yóò di ìyá ọlọ́mọ’? Síbẹ̀ mo bímọ fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀.”

8 Ọmọ náà wá dàgbà, wọ́n sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, Ábúráhámù sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí wọ́n gba ọmú lẹ́nu Ísákì. 9 Àmọ́ Sérà ń kíyè sí i pé ọmọ tí Hágárì+ ará Íjíbítì bí fún Ábúráhámù ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́.+ 10 Ó wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin yìí kò ní bá Ísákì ọmọ mi pín ogún!”+ 11 Àmọ́ ohun tó sọ nípa ọmọ yìí kò dùn mọ́ Ábúráhámù+ nínú rárá. 12 Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sérà ń sọ fún ọ nípa ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ bà ọ́ nínú jẹ́. Fetí sí ohun tó sọ,* torí látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá. 13 Ní ti ọmọ ẹrúbìnrin+ náà, màá mú kí òun náà di orílẹ̀-èdè kan,+ torí ọmọ* rẹ ni.”

14 Ábúráhámù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó mú búrẹ́dì àti ìgò omi tí wọ́n fi awọ ṣe, ó sì fún Hágárì. Ó gbé e lé èjìká rẹ̀, ó sì ní kí òun àti ọmọ+ náà máa lọ. Hágárì kúrò níbẹ̀, ó sì ń rìn kiri nínú aginjù Bíá-ṣébà.+ 15 Nígbà tó yá, omi inú ìgò awọ náà tán, ó sì gbé ọmọ náà sábẹ́ igi kan nínú igbó. 16 Lẹ́yìn náà, ó lọ dá jókòó sí ìwọ̀n ibi tí ọfà lè dé téèyàn bá ta á, torí ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí ọmọ náà kú níṣojú mi.” Torí náà, ó jókòó sí ọ̀ọ́kán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ké, ó sì ń sunkún.

17 Ọlọ́run gbọ́ igbe ọmọ+ náà, áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Hágárì láti ọ̀run, ó sì sọ fún un+ pé: “Ṣé kò sí o, Hágárì? Má bẹ̀rù, torí Ọlọ́run ti gbọ́ igbe ọmọ náà níbi tó wà yẹn. 18 Dìde, gbé ọmọ náà, kí o sì fi ọwọ́ rẹ dì í mú, torí màá mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.”+ 19 Ọlọ́run wá ṣí i lójú, ló bá rí kànga omi kan, ó wá lọ rọ omi kún ìgò awọ náà, ó sì fún ọmọ náà ní omi mu. 20 Ọlọ́run wà pẹ̀lú ọmọ+ náà bó ṣe ń dàgbà. Ó ń gbé inú aginjù, ó sì wá di tafàtafà. 21 Ó ń gbé inú aginjù Páránì,+ ìyá rẹ̀ sì fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Íjíbítì.

22 Nígbà yẹn, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún Ábúráhámù pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+ 23 Torí náà, fi Ọlọ́run búra fún mi báyìí, pé o ò ní hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí èmi àti àwọn ọmọ mi àti àtọmọdọ́mọ mi àti pé o máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí èmi àti ilẹ̀ tí ò ń gbé bí mo ṣe fi hàn sí ọ.”+ 24 Torí náà, Ábúráhámù sọ pé: “Mo búra.”

25 Àmọ́ Ábúráhámù fẹjọ́ sun Ábímélékì nípa kànga omi tí àwọn ìránṣẹ́ Ábímélékì fipá gbà.+ 26 Ábímélékì fèsì pé: “Mi ò mọ ẹni tó ṣe èyí; o ò sọ ọ́ létí mi rí, òní yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́.” 27 Ni Ábúráhámù bá mú àgùntàn àti màlúù, ó kó o fún Ábímélékì, àwọn méjèèjì sì jọ dá májẹ̀mú. 28 Nígbà tí Ábúráhámù ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje sọ́tọ̀ kúrò lára agbo ẹran, 29 Ábímélékì bi Ábúráhámù pé: “Kí nìdí tí o fi ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje yìí sọ́tọ̀?” 30 Ó fèsì pé: “Gba abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà lọ́wọ́ mi, kó jẹ́ ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” 31 Ìdí nìyẹn tó fi pe ibẹ̀ ní Bíá-ṣébà,*+ torí pé àwọn méjèèjì búra níbẹ̀. 32 Torí náà, wọ́n dá májẹ̀mú+ ní Bíá-ṣébà, lẹ́yìn náà, Ábímélékì àti Fíkólì olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbéra, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì.+ 33 Lẹ́yìn náà, ó gbin igi támáríkì kan sí Bíá-ṣébà, ó sì ké pe orúkọ Jèhófà,+ Ọlọ́run ayérayé+ níbẹ̀. 34 Ábúráhámù sì ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì,* ó pẹ́ gan-an*+ níbẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́