ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • A ránṣẹ́ sí Ọba Áhásì (1-9)

        • Ṣeari-jáṣúbù (3)

      • Ohun tí a fi máa dá Ìmánúẹ́lì mọ̀ (10-17)

      • Ohun tó máa gbẹ̀yìn ìwà àìṣòótọ́ (18-25)

Àìsáyà 7:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “wọn kò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 16:1, 2
  • +2Ọb 15:37; 2Kr 28:6
  • +2Ọb 16:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 101-102

Àìsáyà 7:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 102

Àìsáyà 7:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Àṣẹ́kù Nìkan Ló Máa Pa Dà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:18
  • +2Ọb 18:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 102-104

Àìsáyà 7:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 15:30; Ais 8:6, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2006, ojú ìwé 9

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 102-104

Àìsáyà 7:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2013, ojú ìwé 16

Àìsáyà 7:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “dẹ́rù bà á.”

  • *

    Tàbí “ká lu ògiri rẹ̀.” Ní Héb., “ká là á.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 16:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2013, ojú ìwé 16

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 104-105

Àìsáyà 7:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 105

Àìsáyà 7:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:6; Ho 1:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2006, ojú ìwé 9

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 105

Àìsáyà 7:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:23, 24
  • +2Ọb 15:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 105-106

Àìsáyà 7:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 105-106

Àìsáyà 7:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 6:36, 37; Ais 37:30; 38:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 105-106

Àìsáyà 7:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 106

Àìsáyà 7:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 107

Àìsáyà 7:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Omidan náà.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 9:6; Jo 1:14; 1Ti 3:16
  • +Mt 1:23; Lk 1:30-35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2013, ojú ìwé 16-17

    8/15/2011, ojú ìwé 10

    10/1/2008, ojú ìwé 4-5

    12/15/2003, ojú ìwé 5

    11/15/1994, ojú ìwé 29

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 107-108

Àìsáyà 7:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 107-108

Àìsáyà 7:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 15:29; 16:8, 9; Ais 8:3, 4; 17:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 107-108

Àìsáyà 7:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:20
  • +2Ọb 18:13, 14; 2Kr 28:19, 20; Ais 36:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 108-109

Àìsáyà 7:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 109-110

Àìsáyà 7:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 109-110

Àìsáyà 7:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 16:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 110

Àìsáyà 7:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 110-111

Àìsáyà 7:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 110-111

Àìsáyà 7:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 110-111

Àwọn míì

Àìsá. 7:12Ọb 16:1, 2
Àìsá. 7:12Ọb 15:37; 2Kr 28:6
Àìsá. 7:12Ọb 16:5
Àìsá. 7:3Ais 8:18
Àìsá. 7:32Ọb 18:17
Àìsá. 7:42Ọb 15:30; Ais 8:6, 7
Àìsá. 7:62Ọb 16:5
Àìsá. 7:82Ọb 17:6; Ho 1:6
Àìsá. 7:91Ọb 16:23, 24
Àìsá. 7:92Ọb 15:27
Àìsá. 7:11Ond 6:36, 37; Ais 37:30; 38:7, 8
Àìsá. 7:132Kr 36:15, 16
Àìsá. 7:14Ais 9:6; Jo 1:14; 1Ti 3:16
Àìsá. 7:14Mt 1:23; Lk 1:30-35
Àìsá. 7:162Ọb 15:29; 16:8, 9; Ais 8:3, 4; 17:1
Àìsá. 7:171Ọb 12:20
Àìsá. 7:172Ọb 18:13, 14; 2Kr 28:19, 20; Ais 36:1
Àìsá. 7:202Ọb 16:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 7:1-25

Àìsáyà

7 Láyé ìgbà Áhásì+ ọmọ Jótámù ọmọ Ùsáyà, ọba Júdà, Résínì ọba Síríà àti Pékà+ ọmọ Remaláyà, ọba Ísírẹ́lì wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù, àmọ́ kò* ṣẹ́gun rẹ̀.+ 2 Ìròyìn dé ilé Dáfídì pé: “Síríà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfúrémù.”

Jìnnìjìnnì bá ọkàn Áhásì àti ti àwọn èèyàn rẹ̀, wọ́n ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí àwọn igi inú igbó tí atẹ́gùn ń fẹ́ lù.

3 Jèhófà wá sọ fún Àìsáyà pé: “Jọ̀ọ́, jáde lọ pàdé Áhásì, ìwọ àti Ṣeari-jáṣúbù* ọmọ rẹ,+ ní ìpẹ̀kun ibi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà,+ níbi ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀. 4 Kí o sọ fún un pé, ‘Rí i pé o fi ara rẹ lọ́kàn balẹ̀. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ domi torí àwọn ìtì igi méjì tó ń rú èéfín yìí, torí ìbínú Résínì àti Síríà àti ọmọ Remaláyà tó ń ru gùdù.+ 5 Torí Síríà pẹ̀lú Éfúrémù àti ọmọ Remaláyà ti gbìmọ̀ ìkà sí ọ, wọ́n ń sọ pé: 6 “Ẹ jẹ́ ká lọ gbógun ja Júdà, ká fà á ya,* ká ṣẹ́gun rẹ̀* ká gbà á, ká sì fi ọmọ Tábéélì jẹ ọba ibẹ̀.”+

 7 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Kò ní ṣàṣeyọrí,

Kò sì ní ṣẹlẹ̀.

 8 Torí Damásíkù ni orí Síríà,

Résínì sì ni orí Damásíkù.

Kí ọdún márùndínláàádọ́rin (65) tó pé,

Éfúrémù máa fọ́ túútúú, wọn ò sì ní jẹ́ èèyàn mọ́.+

 9 Samáríà+ ni orí Éfúrémù,

Ọmọ Remaláyà sì ni orí Samáríà.+

Tí ìgbàgbọ́ yín ò bá lágbára,

Ẹ ò ní lè fìdí múlẹ̀.”’”

10 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Áhásì lọ pé: 11 “Ní kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ ní àmì kan;+ ó lè jìn bí Isà Òkú,* ó sì lè ga bí ọ̀run.” 12 Àmọ́ Áhásì sọ pé: “Mi ò ní béèrè, mi ò sì ní dán Jèhófà wò.”

13 Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fetí sílẹ̀, ilé Dáfídì. Ṣé bí ẹ ṣe tán àwọn èèyàn ní sùúrù ò tó yín ni? Ṣé ẹ tún fẹ́ tán Ọlọ́run ní sùúrù ni?+ 14 Torí náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ máa fún yín ní àmì kan: Wò ó! Ọ̀dọ́bìnrin náà* máa lóyún, ó sì máa bí ọmọkùnrin kan,+ ó máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.*+ 15 Bọ́tà àti oyin ni á máa jẹ nígbà tó bá fi máa mọ béèyàn ṣe ń kọ ohun búburú, kó sì yan rere. 16 Torí kí ọmọkùnrin náà tó mọ béèyàn ṣe ń kọ ohun búburú, tí á sì yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ò ń bẹ̀rù ni wọ́n máa pa tì pátápátá.+ 17 Jèhófà máa mú kí ìgbà kan dé bá ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ àti ilé bàbá rẹ, èyí tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ọjọ́ tí Éfúrémù ti yapa kúrò lára Júdà,+ torí Ó máa mú ọba Ásíríà wá.+

18 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa súfèé sí àwọn eṣinṣin láti odò Náílì ti ilẹ̀ Íjíbítì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún àti sí àwọn oyin ilẹ̀ Ásíríà, 19 gbogbo wọn sì máa wá bà lé àwọn àfonífojì tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, àwọn pàlàpálá àpáta, gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún àti sórí gbogbo ibi tó lómi.

20 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa lo abẹ tí wọ́n yá láti agbègbè Odò,* ó máa lo ọba Ásíríà,+ láti fá orí àti irun ẹsẹ̀, ó sì máa fá irùngbọ̀n kúrò pẹ̀lú.

21 “Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan máa dá ẹ̀mí ọmọ màlúù kan sí látinú ọ̀wọ́ ẹran àti àgùntàn méjì. 22 Torí pé wàrà pọ̀ gan-an, ó máa jẹ bọ́tà; torí gbogbo èèyàn yòókù nílẹ̀ náà máa jẹ bọ́tà àti oyin.

23 “Ní ọjọ́ yẹn, ibikíbi tí ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàrà bá wà tẹ́lẹ̀, tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà, àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò nìkan ló máa wà níbẹ̀. 24 Àwọn èèyàn máa mú ọrun àti ọfà lọ síbẹ̀, torí pé igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò ló máa wà ní gbogbo ilẹ̀ náà. 25 Ẹ ò ní lè sún mọ́ gbogbo òkè tí wọ́n ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, torí pé ẹ ó máa bẹ̀rù àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò; wọ́n máa di ibi tí àwọn akọ màlúù á ti máa jẹko àti ibi tí àwọn àgùntàn á máa tẹ̀ mọ́lẹ̀.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́