ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Abo màlúù pupa àti omi ìwẹ̀mọ́ (1-22)

Nọ́ńbà 19:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:20; Mal 1:14

Nọ́ńbà 19:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 9:13, 14

Nọ́ńbà 19:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 4:11, 12

Nọ́ńbà 19:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 51:7

Nọ́ńbà 19:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹran ara rẹ̀.”

Nọ́ńbà 19:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹran ara rẹ̀.”

Nọ́ńbà 19:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 9:13, 14
  • +Nọ 19:13, 21

Nọ́ńbà 19:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:49; Le 24:22; Nọ 15:15

Nọ́ńbà 19:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òkú ọkàn èyíkéyìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:1, 11; Nọ 5:2; 6:9; 9:6; 31:19

Nọ́ńbà 19:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi í.”

Nọ́ńbà 19:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òkú, ọkàn ẹnikẹ́ni tó ti kú.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:31
  • +Le 22:3; Heb 10:28
  • +Nọ 19:9

Nọ́ńbà 19:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:31, 32

Nọ́ńbà 19:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 19:11; 31:19

Nọ́ńbà 19:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 19:9
  • +Sm 51:7

Nọ́ńbà 19:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 14:9; Nọ 19:12; 31:19

Nọ́ńbà 19:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 19:13

Nọ́ńbà 19:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 19:18; Heb 9:9, 10, 13, 14

Nọ́ńbà 19:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:4, 5

Àwọn míì

Nọ́ń. 19:2Le 22:20; Mal 1:14
Nọ́ń. 19:4Heb 9:13, 14
Nọ́ń. 19:5Le 4:11, 12
Nọ́ń. 19:6Sm 51:7
Nọ́ń. 19:9Heb 9:13, 14
Nọ́ń. 19:9Nọ 19:13, 21
Nọ́ń. 19:10Ẹk 12:49; Le 24:22; Nọ 15:15
Nọ́ń. 19:11Le 21:1, 11; Nọ 5:2; 6:9; 9:6; 31:19
Nọ́ń. 19:13Le 15:31
Nọ́ń. 19:13Le 22:3; Heb 10:28
Nọ́ń. 19:13Nọ 19:9
Nọ́ń. 19:15Le 11:31, 32
Nọ́ń. 19:16Nọ 19:11; 31:19
Nọ́ń. 19:18Nọ 19:9
Nọ́ń. 19:18Sm 51:7
Nọ́ń. 19:19Le 14:9; Nọ 19:12; 31:19
Nọ́ń. 19:20Nọ 19:13
Nọ́ń. 19:21Nọ 19:18; Heb 9:9, 10, 13, 14
Nọ́ń. 19:22Le 15:4, 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 19:1-22

Nọ́ńbà

19 Jèhófà tún sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Èyí ni àṣẹ tí Jèhófà pa, ‘Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú abo màlúù pupa wá fún ọ, kó jẹ́ èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá tí kò ní àbùkù+ kankan, tí wọn ò sì de àjàgà mọ́ rí. 3 Kí ẹ fún àlùfáà Élíásárì, kó mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kí wọ́n sì pa á níṣojú rẹ̀. 4 Kí àlùfáà Élíásárì wá fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, kó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀méje, sí ọ̀ọ́kán iwájú àgọ́+ ìjọsìn. 5 Kí wọ́n wá sun màlúù náà níṣojú rẹ̀. Kí wọ́n sun+ awọ rẹ̀, ẹran rẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgbẹ́ rẹ̀. 6 Kí àlùfáà wá mú igi kédárì, ewéko hísópù+ àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, kó sì jù ú sínú iná tí wọ́n ti ń sun màlúù náà. 7 Kí àlùfáà wá fọ aṣọ rẹ̀, kó sì fi omi wẹ ara rẹ̀,* lẹ́yìn náà, ó lè wá sínú ibùdó; àmọ́ àlùfáà náà máa jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.

8 “‘Kí ẹni tó sun màlúù náà fi omi fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ ara rẹ̀,* kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.

9 “‘Kí ọkùnrin kan tó mọ́ kó eérú màlúù+ náà jọ, kó sì kó o sí ibi tó mọ́ lẹ́yìn ibùdó, kí àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọ́jú rẹ̀, kí wọ́n sì máa bù ú sínú omi tí wọ́n á fi ṣe ìwẹ̀mọ́.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10 Kí ẹni tó kó eérú màlúù náà jọ fọ aṣọ rẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.

“‘Kí èyí jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì tí wọ́n jọ ń gbé á máa tẹ̀ lé títí lọ.+ 11 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú èèyàn* máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.+ 12 Kí onítọ̀hún fi omi náà* wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta, yóò sì di mímọ́ ní ọjọ́ keje. Àmọ́ tí kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta, kò ní di mímọ́ ní ọjọ́ keje. 13 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú èèyàn èyíkéyìí* tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ ti sọ àgọ́ ìjọsìn+ Jèhófà di aláìmọ́, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà kúrò ní Ísírẹ́lì.+ Torí pé wọn ò tíì wọ́n omi ìwẹ̀mọ́ + sí i lára, ó ṣì jẹ́ aláìmọ́. Àìmọ́ rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀.

14 “‘Òfin tí ẹ máa tẹ̀ lé nìyí tí ẹnì kan bá kú sínú àgọ́: Ẹnikẹ́ni tó bá wọnú àgọ́ náà àti ẹnikẹ́ni tó ti wà nínú àgọ́ náà tẹ́lẹ̀ máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 15 Gbogbo ohun èlò tó wà ní ṣíṣí tí wọn ò fi ìdérí dé jẹ́ aláìmọ́.+ 16 Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá tó sì fara kan ẹni tí wọ́n fi idà pa tàbí òkú tàbí egungun èèyàn tàbí ibi ìsìnkú yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.+ 17 Kí wọ́n bá aláìmọ́ náà bù lára eérú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sun, kí wọ́n fi sínú ohun èlò kan, kí wọ́n sì bu omi tó ń ṣàn sí i. 18 Lẹ́yìn náà, kí ẹnì kan tó mọ́+ mú ewéko hísópù,+ kó kì í bọ inú omi náà, kó sì wọ́n ọn sára àgọ́ náà àti gbogbo ohun èlò àti sára àwọn* tó wà níbẹ̀ àti sára ẹni tó fara kan egungun tàbí ẹni tí wọ́n pa tàbí òkú tàbí ibi ìsìnkú. 19 Kí ẹni tó mọ́ náà wọ́n ọn sára aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje,+ kó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ní ọjọ́ keje; kó wá fọ aṣọ rẹ̀, kó sì fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́ ní alẹ́.

20 “‘Àmọ́ tí ẹnì kan bá jẹ́ aláìmọ́, tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà kúrò láàárín ìjọ,+ torí ó ti sọ ibi mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́. Aláìmọ́ ni torí wọn ò wọ́n omi ìwẹ̀mọ́ sí i lára.

21 “‘Kí èyí jẹ́ àṣẹ tí wọ́n á máa tẹ̀ lé títí lọ: Kí ẹni tó ń wọ́n omi ìwẹ̀mọ́+ fọ aṣọ rẹ̀, kí ẹni tó sì fara kan omi ìwẹ̀mọ́ jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 22 Ohunkóhun tí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ bá fara kàn yóò di aláìmọ́, ẹni* tó bá sì fara kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́