ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

      • Màríà da òróró sí ẹsẹ̀ Jésù (1-11)

      • Jésù gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú (12-19)

      • Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (20-37)

      • Àìnígbàgbọ́ àwọn Júù mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ (38-43)

      • Jésù wá gba ayé là (44-50)

Jòhánù 12:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:1, 43

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 236

Jòhánù 12:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 10:40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 236

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 179

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2011, ojú ìwé 15

Jòhánù 12:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, pọ́n-ùn ti àwọn ará Róòmù, nǹkan bíi gíráàmù 327. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:6-10; Mk 14:3-6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2015, ojú ìwé 13-14

    5/1/2008, ojú ìwé 31

    4/15/2000, ojú ìwé 31

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 236

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1708, 1795

Jòhánù 12:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:47; Mk 14:10; Lk 22:48; Jo 13:29; Iṣe 1:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2005, ojú ìwé 13

    4/15/2000, ojú ìwé 31

Jòhánù 12:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún B14.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2008, ojú ìwé 31

    6/1/2005, ojú ìwé 13

    4/15/2000, ojú ìwé 31

Jòhánù 12:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2015, ojú ìwé 29-30

Jòhánù 12:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:12; Mk 14:8; Jo 19:40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2000, ojú ìwé 16

Jòhánù 12:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:11
  • +Mt 26:11; Mk 14:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2003, ojú ìwé 32

Jòhánù 12:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:43, 44

Jòhánù 12:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 7:31; 11:44, 45

Jòhánù 12:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún A5.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 118:25, 26
  • +Mt 21:8, 9; Mk 11:8, 9; Jo 1:49

Jòhánù 12:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 21:7; Mk 11:7; Lk 19:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 238

Jòhánù 12:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “agódóńgbó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 1:33, 34; Ais 62:11; Sek 9:9; Mt 21:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 238

Jòhánù 12:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 7:39
  • +Lk 24:45; Jo 14:26

Jòhánù 12:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ibojì ìrántí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:1, 43
  • +Mt 21:15; Lk 19:37

Jòhánù 12:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:48

Jòhánù 12:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2015, ojú ìwé 21

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 240

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1700

Jòhánù 12:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:44

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2015, ojú ìwé 21

Jòhánù 12:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 240

Jòhánù 12:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 13:31, 32; 17:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2000, ojú ìwé 10-11

Jòhánù 12:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 16:21; Ro 14:9; 1Kọ 15:36

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 240

Jòhánù 12:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 12:11
  • +Mt 16:25; Mk 8:35; Lk 9:24

Jòhánù 12:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:3; 17:24; 1Tẹ 4:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 240-241

Jòhánù 12:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:38; Mk 14:34
  • +Lk 12:50; 22:41, 42; Heb 5:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 241

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2010, ojú ìwé 11

    9/15/2000, ojú ìwé 18

Jòhánù 12:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 3:17; 17:5; Mk 1:11; 9:7; Lk 3:22; 9:35; 2Pe 1:17
  • +Jo 17:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2019, ojú ìwé 11-13

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2010, ojú ìwé 11

Jòhánù 12:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

Jòhánù 12:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:30; 16:11; Iṣe 26:17, 18; 2Kọ 4:3, 4; Ef 2:1, 2; 1Jo 5:19
  • +Lk 10:18; Ifi 12:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2009, ojú ìwé 23

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 75-76

Jòhánù 12:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 8:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

Jòhánù 12:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 5:30

Jòhánù 12:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:35, 36; 110:4; Ais 9:7
  • +Jo 3:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

Jòhánù 12:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

Jòhánù 12:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 5:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 32

Jòhánù 12:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún A5.

  • *

    Tàbí “nínú ìròyìn wa?”

  • *

    Wo Àfikún A5.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 10:16
  • +Ais 53:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2011, ojú ìwé 11

    10/1/2008, ojú ìwé 5

Jòhánù 12:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:10; Mt 13:14; Mk 4:11, 12; Iṣe 28:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

Jòhánù 12:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:1, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/1998, ojú ìwé 24

Jòhánù 12:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 19:38
  • +Jo 9:22; 16:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 242

Jòhánù 12:43

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 5:44

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/1998, ojú ìwé 16-17

Jòhánù 12:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 10:40; Mk 9:37

Jòhánù 12:45

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:9

Jòhánù 12:46

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:19; 8:12; 9:5
  • +Jo 12:35

Jòhánù 12:47

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:16, 17

Jòhánù 12:49

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 8:38; 14:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 15

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2008, ojú ìwé 13

Jòhánù 12:50

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 6:40
  • +Jo 3:34

Àwọn míì

Jòh. 12:1Jo 11:1, 43
Jòh. 12:2Lk 10:40
Jòh. 12:3Mt 26:6-10; Mk 14:3-6
Jòh. 12:4Mt 26:47; Mk 14:10; Lk 22:48; Jo 13:29; Iṣe 1:16
Jòh. 12:7Mt 26:12; Mk 14:8; Jo 19:40
Jòh. 12:8Di 15:11
Jòh. 12:8Mt 26:11; Mk 14:7
Jòh. 12:9Jo 11:43, 44
Jòh. 12:11Jo 7:31; 11:44, 45
Jòh. 12:13Sm 118:25, 26
Jòh. 12:13Mt 21:8, 9; Mk 11:8, 9; Jo 1:49
Jòh. 12:14Mt 21:7; Mk 11:7; Lk 19:35
Jòh. 12:151Ọb 1:33, 34; Ais 62:11; Sek 9:9; Mt 21:5
Jòh. 12:16Jo 7:39
Jòh. 12:16Lk 24:45; Jo 14:26
Jòh. 12:17Jo 11:1, 43
Jòh. 12:17Mt 21:15; Lk 19:37
Jòh. 12:19Jo 11:48
Jòh. 12:21Jo 1:44
Jòh. 12:23Jo 13:31, 32; 17:1
Jòh. 12:24Mt 16:21; Ro 14:9; 1Kọ 15:36
Jòh. 12:25Ifi 12:11
Jòh. 12:25Mt 16:25; Mk 8:35; Lk 9:24
Jòh. 12:26Jo 14:3; 17:24; 1Tẹ 4:17
Jòh. 12:27Mt 26:38; Mk 14:34
Jòh. 12:27Lk 12:50; 22:41, 42; Heb 5:7
Jòh. 12:28Mt 3:17; 17:5; Mk 1:11; 9:7; Lk 3:22; 9:35; 2Pe 1:17
Jòh. 12:28Jo 17:1
Jòh. 12:31Jo 14:30; 16:11; Iṣe 26:17, 18; 2Kọ 4:3, 4; Ef 2:1, 2; 1Jo 5:19
Jòh. 12:31Lk 10:18; Ifi 12:9
Jòh. 12:32Jo 8:28
Jòh. 12:33Iṣe 5:30
Jòh. 12:34Sm 89:35, 36; 110:4; Ais 9:7
Jòh. 12:34Jo 3:14
Jòh. 12:35Jo 11:10
Jòh. 12:36Ef 5:8
Jòh. 12:38Ro 10:16
Jòh. 12:38Ais 53:1
Jòh. 12:40Ais 6:10; Mt 13:14; Mk 4:11, 12; Iṣe 28:27
Jòh. 12:41Ais 6:1, 8
Jòh. 12:42Jo 19:38
Jòh. 12:42Jo 9:22; 16:2
Jòh. 12:43Jo 5:44
Jòh. 12:44Mt 10:40; Mk 9:37
Jòh. 12:45Jo 14:9
Jòh. 12:46Jo 3:19; 8:12; 9:5
Jòh. 12:46Jo 12:35
Jòh. 12:47Jo 3:16, 17
Jòh. 12:49Jo 8:38; 14:10
Jòh. 12:50Jo 6:40
Jòh. 12:50Jo 3:34
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
  • 48
  • 49
  • 50
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jòhánù 12:1-50

Àkọsílẹ̀ Jòhánù

12 Nígbà tí Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jésù dé sí Bẹ́tánì, níbi tí Lásárù+ wà, ẹni tí Jésù jí dìde. 2 Torí náà, wọ́n se àsè oúnjẹ alẹ́ fún un níbẹ̀, Màtá ń gbé oúnjẹ wá fún wọn,+ Lásárù sì wà lára àwọn tó ń bá a jẹun.* 3 Màríà wá mú ìwọ̀n pọ́n-ùn kan* òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an, ó dà á sí ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ. Òórùn òróró onílọ́fínńdà náà wá gba inú ilé náà kan.+ 4 Àmọ́ Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó máa tó dà á, sọ pé: 5 “Kí ló dé tí a ò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì,* ká sì fún àwọn aláìní?” 6 Kì í ṣe torí pé ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún ló ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí o, àmọ́ torí pé olè ni, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó wà, ó sì máa ń jí owó inú rẹ̀. 7 Torí náà, Jésù sọ pé: “Fi í sílẹ̀, kó lè ṣe èyí nítorí ọjọ́ ìsìnkú mi.+ 8 Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.”+

9 Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, wọ́n sì wá, àmọ́ kì í ṣe torí Jésù nìkan, wọ́n tún fẹ́ rí Lásárù, ẹni tí Jésù jí dìde.+ 10 Àwọn olórí àlùfáà wá gbìmọ̀ láti pa Lásárù náà, 11 ìdí ni pé torí rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù ṣe ń lọ síbẹ̀, tí wọ́n sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù.+

12 Lọ́jọ́ kejì, èrò rẹpẹtẹ tó wá síbi àjọyọ̀ náà gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù. 13 Wọ́n wá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là! Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà,*+ Ọba Ísírẹ́lì!”+ 14 Nígbà tí Jésù rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó jókòó sórí rẹ̀,+ bí a ṣe kọ ọ́ pé: 15 “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì. Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀, ó jókòó sórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”*+ 16 Àwọn nǹkan yìí ò kọ́kọ́ yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àmọ́ nígbà tí a ṣe Jésù lógo,+ wọ́n rántí pé a ti kọ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀ àti pé wọ́n ṣe àwọn nǹkan yìí sí i.+

17 Àwọn èrò tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó pe Lásárù jáde látinú ibojì,*+ tó sì jí i dìde ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ ṣáá.+ 18 Ìdí nìyí tí àwọn èrò náà tún fi lọ bá a, torí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí. 19 Torí náà, àwọn Farisí sọ láàárín ara wọn pé: “Ṣé ẹ rí i pé ẹ ò ṣe àṣeyọrí kankan. Ẹ wò ó! Gbogbo ayé ti gba tiẹ̀.”+

20 Àwọn Gíríìkì kan wà lára àwọn tó wá jọ́sìn níbi àjọyọ̀ náà. 21 Torí náà, àwọn yìí wá bá Fílípì,+ ẹni tó wá láti Bẹtisáídà ti Gálílì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Ọ̀gá, a fẹ́ rí Jésù.” 22 Fílípì wá, ó sì sọ fún Áńdérù. Áńdérù àti Fílípì wá sọ fún Jésù.

23 Àmọ́ Jésù dá wọn lóhùn pé: “Wákàtí náà ti dé tí a máa ṣe Ọmọ èèyàn lógo.+ 24 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé hóró àlìkámà* kan bọ́ sílẹ̀, kó sì kú, ó ṣì máa jẹ́ ẹyọ hóró kan ṣoṣo; àmọ́ tó bá kú,+ ìgbà yẹn ló máa so èso púpọ̀. 25 Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn ẹ̀mí* rẹ̀ ń pa á run, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá kórìíra ẹ̀mí* rẹ̀+ nínú ayé yìí máa pa á mọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.+ 26 Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, kó máa tẹ̀ lé mi, ibi tí mo bá sì wà ni ìránṣẹ́ mi náà máa wà.+ Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, Baba máa bọlá fún un. 27 Ní báyìí, ìdààmú bá mi,*+ kí sì ni kí n sọ? Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí.+ Síbẹ̀, torí èyí ni mo fi wá sí wákàtí yìí. 28 Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ni ohùn kan+ bá dún láti ọ̀run pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.”+

29 Àwọn èrò tó dúró síbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé ààrá ti sán. Àwọn míì sọ pé: “Áńgẹ́lì kan ti bá a sọ̀rọ̀.” 30 Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe torí tèmi ni ohùn yìí ṣe dún, torí tiyín ni. 31 Ní báyìí, à ń ṣèdájọ́ ayé yìí; ní báyìí, a máa lé alákòóso ayé yìí + jáde.+ 32 Síbẹ̀, tí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé,+ màá fa onírúurú èèyàn sọ́dọ̀ ara mi.” 33 Ní tòótọ́, ó ń sọ èyí láti jẹ́ kí wọ́n mọ irú ikú tó máa tó kú.+ 34 Àwọn èrò náà wá dá a lóhùn pé: “A gbọ́ látinú Òfin pé Kristi máa wà títí láé.+ Kí ló dé tí o wá sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè?+ Ta ni Ọmọ èèyàn yìí?” 35 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ìmọ́lẹ̀ máa wà láàárín yín fúngbà díẹ̀ sí i. Ẹ rìn nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀ náà, kí òkùnkùn má bàa borí yín; ẹnikẹ́ni tó bá ń rìn nínú òkùnkùn kò mọ ibi tí òun ń lọ.+ 36 Nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ náà, kí ẹ lè di ọmọ ìmọ́lẹ̀.”+

Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ fara pa mọ́ fún wọn. 37 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì níwájú wọn, wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, 38 kí ọ̀rọ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: “Jèhófà,* ta ló ti nígbàgbọ́ nínú ohun tó gbọ́ lọ́dọ̀ wa?*+ Ní ti apá Jèhófà,* ta la ti ṣí i payá fún?”+ 39 Ìdí tí wọn ò fi gbà gbọ́ ni pé Àìsáyà tún sọ pé: 40 “Ó ti fọ́ ojú wọn, ó sì ti mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran, kí ọkàn wọn má sì lóye, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.”+ 41 Àìsáyà sọ àwọn nǹkan yìí torí pé ó rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ 42 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn alákòóso pàápàá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lóòótọ́,+ àmọ́ wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí àwọn Farisí, kí wọ́n má bàa lé wọn kúrò nínú sínágọ́gù;+ 43 torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo èèyàn pàápàá ju ògo Ọlọ́run lọ.+

44 Àmọ́ Jésù gbóhùn sókè, ó sì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, kò ní ìgbàgbọ́ nínú èmi nìkan, àmọ́ ó tún ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán mi;+ 45 ẹnikẹ́ni tó bá sì rí mi, ó rí Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ 46 Mo wá sínú ayé bí ìmọ́lẹ̀,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú mi má bàa wà nínú òkùnkùn.+ 47 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa á mọ́, mi ò ní dá a lẹ́jọ́; torí pé mi ò wá láti dá ayé lẹ́jọ́, àmọ́ láti gba ayé là.+ 48 Ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, tí kò sì gba àwọn ọ̀rọ̀ mi ní ẹni tó máa dá a lẹ́jọ́. Ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ló máa dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 49 Torí èrò ara mi kọ́ ni mò ń sọ, àmọ́ Baba tó rán mi fúnra rẹ̀ ti fún mi ní àṣẹ kan nípa ohun tí màá wí àti ohun tí màá sọ.+ 50 Mo sì mọ̀ pé àṣẹ rẹ̀ túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.+ Torí náà, ohunkóhun tí mo bá sọ, bí Baba ṣe sọ fún mi gẹ́lẹ́ ni mo sọ ọ́.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́