ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Omi ń fà (1-14)

        • Nóà rán àdàbà jáde (8-12)

      • Wọ́n ń kúrò nínú áàkì (15-19)

      • Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún ayé (20-22)

Jẹ́nẹ́sísì 8:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “rántí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:19, 20; Heb 11:7

Jẹ́nẹ́sísì 8:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òjò sì dáwọ́ dúró.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:11, 12

Jẹ́nẹ́sísì 8:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2003, ojú ìwé 5

Jẹ́nẹ́sísì 8:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 14

    7/1/2009, ojú ìwé 13-14

    5/15/2003, ojú ìwé 5

Jẹ́nẹ́sísì 8:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 14

    5/15/2003, ojú ìwé 5

Jẹ́nẹ́sísì 8:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:16

Jẹ́nẹ́sísì 8:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    1/8/1997, ojú ìwé 23-24

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1992, ojú ìwé 31

Jẹ́nẹ́sísì 8:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1992, ojú ìwé 31

Jẹ́nẹ́sísì 8:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1992, ojú ìwé 31

Jẹ́nẹ́sísì 8:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:20; 8:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2004, ojú ìwé 31

    1/1/2004, ojú ìwé 31

Jẹ́nẹ́sísì 8:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:6, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 14

    5/15/2003, ojú ìwé 5

Jẹ́nẹ́sísì 8:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 14

    5/15/2003, ojú ìwé 5

Jẹ́nẹ́sísì 8:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:7; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5

Jẹ́nẹ́sísì 8:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbá yìn-ìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:19, 20; 7:14, 15
  • +Jẹ 1:22

Jẹ́nẹ́sísì 8:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:10

Jẹ́nẹ́sísì 8:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:13, 14

Jẹ́nẹ́sísì 8:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:7
  • +Jẹ 7:2; Le 20:25
  • +Di 27:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 15

Jẹ́nẹ́sísì 8:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

  • *

    Tàbí “pe ibi wá sórí ilẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:17; 5:29
  • +Jẹ 6:5; Onw 7:20; Mt 15:19
  • +Jẹ 6:7, 17; 9:11; Ais 54:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2017, ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 15

    11/1/1996, ojú ìwé 7-8

Jẹ́nẹ́sísì 8:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:14; Sm 74:17; Onw 1:4

Àwọn míì

Jẹ́n. 8:1Jẹ 6:19, 20; Heb 11:7
Jẹ́n. 8:2Jẹ 7:11, 12
Jẹ́n. 8:5Jẹ 7:20
Jẹ́n. 8:6Jẹ 6:16
Jẹ́n. 8:9Jẹ 7:19
Jẹ́n. 8:11Jẹ 7:20; 8:3
Jẹ́n. 8:13Jẹ 7:6, 11
Jẹ́n. 8:16Jẹ 7:7; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5
Jẹ́n. 8:17Jẹ 6:19, 20; 7:14, 15
Jẹ́n. 8:17Jẹ 1:22
Jẹ́n. 8:18Jẹ 6:10
Jẹ́n. 8:19Jẹ 7:13, 14
Jẹ́n. 8:20Jẹ 12:7
Jẹ́n. 8:20Jẹ 7:2; Le 20:25
Jẹ́n. 8:20Di 27:6
Jẹ́n. 8:21Jẹ 3:17; 5:29
Jẹ́n. 8:21Jẹ 6:5; Onw 7:20; Mt 15:19
Jẹ́n. 8:21Jẹ 6:7, 17; 9:11; Ais 54:9
Jẹ́n. 8:22Jẹ 1:14; Sm 74:17; Onw 1:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 8:1-22

Jẹ́nẹ́sísì

8 Àmọ́ Ọlọ́run yí àfiyèsí rẹ̀ sí* Nóà àti gbogbo ẹran inú igbó àti ẹran ọ̀sìn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú áàkì,+ Ọlọ́run sì mú kí atẹ́gùn fẹ́ sórí ayé, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fà. 2 Àwọn orísun omi àti àwọn ibodè omi ọ̀run tì pa, òjò ò sì rọ̀ mọ́* láti ọ̀run.+ 3 Omi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn àádọ́jọ (150) ọjọ́, omi náà ti lọ sílẹ̀. 4 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje, áàkì náà gúnlẹ̀ sórí àwọn òkè Árárátì. 5 Omi náà ń lọ sílẹ̀ ṣáá títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá, téńté àwọn òkè fara hàn.+

6 Lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́, Nóà ṣí fèrèsé*+ tó ṣe sí áàkì náà, 7 ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde; ẹyẹ náà ń fò jáde, ó sì ń pa dà wá títí omi náà fi gbẹ lórí ilẹ̀.

8 Lẹ́yìn náà, ó rán àdàbà kan jáde kó lè mọ̀ bóyá omi náà ti fà lórí ilẹ̀. 9 Àdàbà náà ò rí ibi ìsinmi kankan tó lè bà lé,* torí náà, ó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú áàkì torí omi ṣì bo gbogbo ayé.+ Ó wá na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un wọlé sínú áàkì. 10 Ó dúró fún ọjọ́ méje, ó sì rán àdàbà náà jáde lẹ́ẹ̀kan sí i látinú áàkì. 11 Nígbà tí àdàbà náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ó rí i pé ewé ólífì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ já wà ní ẹnu rẹ̀! Nóà wá mọ̀ pé omi náà ti lọ sílẹ̀.+ 12 Ó tún dúró fún ọjọ́ méje míì. Ó wá rán àdàbà náà jáde, àmọ́ kò pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

13 Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, ọdún kọkànlélẹ́gbẹ̀ta (601),+ omi náà ti fà lórí ilẹ̀; Nóà ṣí ìbòrí áàkì náà, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti ń gbẹ. 14 Ilẹ̀ náà wá gbẹ tán ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kejì.

15 Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé: 16 “Jáde nínú áàkì, ìwọ, ìyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.+ 17 Kó onírúurú ẹran ara+ tó jẹ́ ohun alààyè jáde pẹ̀lú rẹ, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, àwọn ẹran àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa pọ̀ sí i* ní ayé, kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n sì pọ̀ ní ayé.”+

18 Torí náà, Nóà jáde, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀. 19 Gbogbo ohun alààyè, gbogbo ẹran tó ń rákò, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò àti gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀ jáde nínú áàkì náà lọ́wọ̀ọ̀wọ́.+ 20 Nóà sì mọ pẹpẹ+ kan fún Jèhófà, ó mú lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti lára gbogbo ẹ̀dá tó ń fò+ tó sì mọ́, ó sì rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.+ 21 Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ òórùn dídùn.* Jèhófà wá sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Mi ò tún ní fi ilẹ̀+ gégùn-ún* mọ́ torí èèyàn, torí pé kìkì ibi ni èèyàn ń rò lọ́kàn láti ìgbà èwe rẹ̀ wá;+ mi ò sì tún ní pa gbogbo ohun alààyè run mọ́, bí mo ti ṣe.+ 22 Láti ìsinsìnyí lọ, ìgbà ìfúnrúgbìn àti ìgbà ìkórè kò ní tán ní ayé, bẹ́ẹ̀ ni òtútù àti ooru, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù, ọ̀sán àti òru.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́