Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà
3 Torí náà, nígbà tí a ò lè mú un mọ́ra mọ́, a rí i pé á dára kí àwa nìkan dúró sí Áténì;+ 2 a sì rán Tímótì,+ arákùnrin wa àti òjíṣẹ́* Ọlọ́run nínú ìhìn rere nípa Kristi, kí ó lè mú kí ẹ fìdí múlẹ̀,* kí ó sì tù yín nínú nítorí ìgbàgbọ́ yín, 3 kí àwọn ìpọ́njú yìí má bàa mú ẹnì kankan yẹsẹ̀.* Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé kò sí bí a ò ṣe ní jìyà irú àwọn nǹkan yìí.*+ 4 Nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń sọ fún yín pé a máa ní ìpọ́njú, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn, bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀.+ 5 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí mi ò lè mú un mọ́ra mọ́, mo ránṣẹ́ kí n lè mọ̀ nípa ìdúróṣinṣin yín,+ pé bóyá lọ́nà kan, Adánniwò+ lè ti dán yín wò, kí làálàá wa sì ti já sí asán.
6 Àmọ́ Tímótì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ọ̀dọ̀ wa látọ̀dọ̀ yín ni,+ ó sì ti fún wa ní ìròyìn ayọ̀ nípa ìdúróṣinṣin yín àti ìfẹ́ yín, pé ìgbà gbogbo ni inú yín máa ń dùn tí ẹ bá rántí wa, àárò wa sì ń sọ yín bí tiyín ṣe ń sọ àwa náà. 7 Ẹ̀yin ará, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nínú gbogbo wàhálà* wa àti ìpọ́njú wa, a ti rí ìtùnú gbà nítorí yín àti nítorí ìdúróṣinṣin tí ẹ ní.+ 8 Torí pé à ń mú wa sọ jí,* tí ẹ bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa. 9 Báwo ni ká ṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí yín lórí ayọ̀ púpọ̀ tí ẹ̀ ń mú ká ní níwájú Ọlọ́run wa? 10 Tọ̀sántòru là ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ taratara ká lè fojú kàn yín,* ká sì fún yín ní àwọn ohun tí á mú kí ìgbàgbọ́ yín lágbára.+
11 Tóò, kí Ọlọ́run àti Baba wa fúnra rẹ̀ àti Jésù Olúwa wa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti wá sọ́dọ̀ yín. 12 Yàtọ̀ síyẹn, kí Olúwa mú kí ẹ pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni, kí ó mú kí ẹ pọ̀ gidigidi nínú ìfẹ́ sí ara yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan+ àti sí gbogbo èèyàn, bí àwa náà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, 13 kí ó lè mú kí ọkàn yín fìdí múlẹ̀, kí ó jẹ́ aláìlẹ́bi nínú jíjẹ́ mímọ́ níwájú Ọlọ́run+ àti Baba wa nígbà tí Jésù Olúwa wa+ bá wà níhìn-ín pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.