ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Páṣúrì lu Jeremáyà (1-6)

      • Jeremáyà ò lè dákẹ́ ìwàásù (7-13)

        • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí iná tó ń jó (9)

        • Jèhófà dà bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù (11)

      • Jeremáyà mú ẹjọ́ rẹ̀ wá (14-18)

Jeremáyà 20:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 16:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1692

    Jeremáyà, ojú ìwé 57-58, 84

Jeremáyà 20:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:25

Jeremáyà 20:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:32
  • +Jer 25:9; 39:9

Jeremáyà 20:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:17; 24:11, 13; 25:13-15; Ida 1:10
  • +2Kr 36:10; Jer 15:13

Jeremáyà 20:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 14:14; 28:15; 29:21

Jeremáyà 20:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 3:14; Mik 3:8
  • +Sm 22:7; Jer 15:10, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 36-37

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 9

Jeremáyà 20:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:16; Jer 6:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 118

Jeremáyà 20:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:2, 4; Jon 1:3
  • +Jer 6:11; Emọ 3:8; Iṣe 4:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2010, ojú ìwé 9

    2/15/2010, ojú ìwé 7-8

    7/1/2000, ojú ìwé 9-10

    3/1/2000, ojú ìwé 17

    Jeremáyà, ojú ìwé 118

Jeremáyà 20:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 31:13
  • +Sm 38:16

Jeremáyà 20:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:8; Ro 8:31
  • +Sm 27:2; Jer 15:15, 20; 17:18
  • +Sm 6:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2011, ojú ìwé 30

    Jeremáyà, ojú ìwé 36-37

Jeremáyà 20:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “inú lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 17:10
  • +Sm 59:10; Jer 17:18
  • +Jer 11:20; 1Pe 2:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 147-148

Jeremáyà 20:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn àwọn aláìní.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 86

Jeremáyà 20:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 3:3; Jer 15:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 9-10

Jeremáyà 20:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 10:18

Jeremáyà 20:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 3:20

Àwọn míì

Jer. 20:22Kr 16:10
Jer. 20:3Jer 6:25
Jer. 20:4Di 28:32
Jer. 20:4Jer 25:9; 39:9
Jer. 20:52Ọb 20:17; 24:11, 13; 25:13-15; Ida 1:10
Jer. 20:52Kr 36:10; Jer 15:13
Jer. 20:6Jer 14:14; 28:15; 29:21
Jer. 20:7Isk 3:14; Mik 3:8
Jer. 20:7Sm 22:7; Jer 15:10, 15
Jer. 20:82Kr 36:16; Jer 6:10
Jer. 20:91Ọb 19:2, 4; Jon 1:3
Jer. 20:9Jer 6:11; Emọ 3:8; Iṣe 4:19, 20
Jer. 20:10Sm 31:13
Jer. 20:10Sm 38:16
Jer. 20:11Jer 1:8; Ro 8:31
Jer. 20:11Sm 27:2; Jer 15:15, 20; 17:18
Jer. 20:11Sm 6:10
Jer. 20:12Jer 17:10
Jer. 20:12Sm 59:10; Jer 17:18
Jer. 20:12Jer 11:20; 1Pe 2:23
Jer. 20:14Job 3:3; Jer 15:10
Jer. 20:17Job 10:18
Jer. 20:18Job 3:20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 20:1-18

Jeremáyà

20 Ó ṣẹlẹ̀ pé Páṣúrì, ọmọ Ímérì, àlùfáà, tó tún jẹ́ olórí àwọn kọmíṣọ́nnà nínú ilé Jèhófà fetí sí Jeremáyà nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan yìí. 2 Ni Páṣúrì bá lu wòlíì Jeremáyà, ó sì fi í sínú àbà+ tó wà ní Ẹnubodè Òkè ti Bẹ́ńjámínì, tó wà ní ilé Jèhófà. 3 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, nígbà tí Páṣúrì tú Jeremáyà sílẹ̀ nínú àbà, Jeremáyà sọ fún un pé:

“Jèhófà ti fún ọ lórúkọ, o kì í ṣe Páṣúrì mọ́, bí kò ṣe Ẹ̀rù Yí Mi Ká.+ 4 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá sọ ọ́ di ohun ẹ̀rù sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn ọ̀tá wọn á sì fi idà pa wọ́n ní ìṣojú rẹ.+ Màá fa gbogbo Júdà lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, á sì fi idà pa wọ́n.+ 5 Màá fi gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun iyebíye rẹ̀ àti gbogbo ìṣúra àwọn ọba Júdà lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.+ Wọ́n á gba tọwọ́ wọn, wọ́n á mú wọn, wọ́n á sì kó wọn lọ sí Bábílónì.+ 6 Ní tìrẹ, ìwọ Páṣúrì àti gbogbo àwọn tó ń gbé inú ilé rẹ, ẹ ó lọ sí oko ẹrú. Wàá lọ sí Bábílónì, ibẹ̀ ni wàá kú sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n á sin ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sí torí o ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún wọn.’”+

 7 O ti yà mí lẹ́nu, Jèhófà, ẹnu sì yà mí.

O lo agbára rẹ lórí mi, o sì borí.+

Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;

Gbogbo èèyàn ló ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.+

 8 Nítorí nígbàkigbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ṣe ni mò ń ké jáde, tí mo sì ń kéde pé,

“Ìwà ipá àti ìparun!”

Nítorí pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ohun tó ń fa èébú àti yẹ̀yẹ́ fún mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+

 9 Torí náà, mo sọ pé: “Mi ò ní sọ nípa rẹ̀ mọ́,

Mi ò sì ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́.”+

Àmọ́ nínú ọkàn mi, ńṣe ló dà bí iná tó ń jó, tí wọ́n sé mọ́ inú egungun mi,

Mi ò lè pa á mọ́ra mọ́,

Mi ò sì lè fara dà á mọ́.+

10 Nítorí mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àhesọ ọ̀rọ̀ tó burú;

Ohun ẹ̀rù yí mi ká.+

“Ẹ fẹ̀sùn kàn án; ẹ jẹ́ ká fẹ̀sùn kàn án!”

Gbogbo àwọn tó ń sọ pé àwọn fẹ́ àlàáfíà fún mi, ìṣubú mi ni wọ́n ń wá:+

“Bóyá ó máa ṣàṣìṣe torí pé kò kíyè sára,

Tí a ó sì lè borí rẹ̀, kí a sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”

11 Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù.+

Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi á fi fẹsẹ̀ kọ, wọn ò sì ní borí.+

Ojú á tì wọ́n wẹ̀lẹ̀mù, torí pé wọn ò ní ṣàṣeyọrí.

Wọ́n á tẹ́ títí láé, ẹ̀tẹ́ wọn ò sì ní ṣeé gbàgbé.+

12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ń ṣàyẹ̀wò àwọn olódodo;

Ò ń rí èrò inú* àti ọkàn.+

Jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lára wọn,+

Nítorí ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹjọ́ mi lé.+

13 Ẹ kọrin sí Jèhófà! Ẹ yin Jèhófà!

Nítorí ó ti gba àwọn aláìní* sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.

14 Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi!

Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má gba ìbùkún! +

15 Ègún ni fún ọkùnrin tó mú ìròyìn ayọ̀ wá fún bàbá mi pé:

“Ìyàwó rẹ ti bímọ, ọkùnrin ló bí!”

Tó mú inú rẹ̀ dùn gidigidi.

16 Kí ọkùnrin yẹn dà bí àwọn ìlú tí Jèhófà wó lulẹ̀ láìkẹ́dùn.

Kí ó gbọ́ igbe ẹkún ní òwúrọ̀ àti ìró ogun ní ọ̀sán gangan.

17 Kí nìdí tí ò kúkú fi pa mí nígbà tí mo wà nínú ikùn,

Kí inú ìyá mi lè di ibi ìsìnkú mi

Kí oyún wà nínú ikùn rẹ̀ nígbà gbogbo?+

18 Kí nìdí tí mo fi jáde kúrò nínú ikùn

Láti rí ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn,

Láti mú kí àwọn ọjọ́ mi dópin nínú ìtìjú?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́