ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Amọ̀ tó wà lọ́wọ́ amọ̀kòkò (1-12)

      • Jèhófà kẹ̀yìn sí Ísírẹ́lì (13-17)

      • Wọ́n gbìmọ̀ ibi sí Jeremáyà; ó ké pe Ọlọ́run (18-23)

Jeremáyà 18:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 19:1

Jeremáyà 18:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “bó ṣe tọ́ ní ojú amọ̀kòkò náà láti ṣe.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 4/2017, ojú ìwé 1

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/1999, ojú ìwé 22

Jeremáyà 18:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 9:20, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 4/2017, ojú ìwé 1

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    4/2017, ojú ìwé 3

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/1999, ojú ìwé 22

Jeremáyà 18:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:10; 12:14; 25:9; 45:4

Jeremáyà 18:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:33, 34; Sm 106:45; Jer 7:3; 26:3; Isk 18:21; Joẹ 2:13; Jon 3:5, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 4/2017, ojú ìwé 1

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    4/2017, ojú ìwé 3

    Jeremáyà, ojú ìwé 151

Jeremáyà 18:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 4/2017, ojú ìwé 1

Jeremáyà 18:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:16; Isk 18:23

Jeremáyà 18:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:25
  • +Di 29:19, 20; Jer 7:24

Jeremáyà 18:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:13

Jeremáyà 18:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”

  • *

    Tàbí “tí wọn kò ṣe.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:19; 3:21
  • +Jer 10:14, 15
  • +Jer 6:16

Jeremáyà 18:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:33; Isk 6:14
  • +1Ọb 9:8; Jer 19:8; Ida 2:15; Mik 6:16
  • +Di 28:37

Jeremáyà 18:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:17

Jeremáyà 18:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

  • *

    Ní Héb., “fi ahọ́n lù ú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 11:19

Jeremáyà 18:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 35:7

Jeremáyà 18:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 12:3
  • +Ida 5:3
  • +2Kr 36:17

Jeremáyà 18:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akónilẹ́rù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 38:12

Jeremáyà 18:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 11:19, 20
  • +Sm 35:4
  • +Jer 15:15

Àwọn míì

Jer. 18:2Jer 19:1
Jer. 18:6Ro 9:20, 21
Jer. 18:7Jer 1:10; 12:14; 25:9; 45:4
Jer. 18:81Ọb 8:33, 34; Sm 106:45; Jer 7:3; 26:3; Isk 18:21; Joẹ 2:13; Jon 3:5, 10
Jer. 18:11Ais 1:16; Isk 18:23
Jer. 18:12Jer 2:25
Jer. 18:12Di 29:19, 20; Jer 7:24
Jer. 18:13Jer 2:13
Jer. 18:15Jer 2:19; 3:21
Jer. 18:15Jer 10:14, 15
Jer. 18:15Jer 6:16
Jer. 18:16Le 26:33; Isk 6:14
Jer. 18:161Ọb 9:8; Jer 19:8; Ida 2:15; Mik 6:16
Jer. 18:16Di 28:37
Jer. 18:17Di 31:17
Jer. 18:18Jer 11:19
Jer. 18:20Sm 35:7
Jer. 18:21Jer 12:3
Jer. 18:21Ida 5:3
Jer. 18:212Kr 36:17
Jer. 18:22Sm 38:12
Jer. 18:23Jer 11:19, 20
Jer. 18:23Sm 35:4
Jer. 18:23Jer 15:15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 18:1-23

Jeremáyà

18 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní: 2 “Dìde, kí o sì lọ sí ilé amọ̀kòkò,+ ibẹ̀ sì ni màá ti jẹ́ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”

3 Torí náà, mo lọ sí ilé amọ̀kòkò, ó sì ń ṣiṣẹ́ lórí àgbá kẹ̀kẹ́ amọ̀kòkò. 4 Àmọ́, ohun tí amọ̀kòkò ń fi amọ̀ ṣe bà jẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Amọ̀kòkò náà wá fi ṣe ohun míì, bó ṣe dáa lójú rẹ̀.*

5 Ìgbà náà ni Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 6 “‘Ṣé mi ò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ni, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí. ‘Wò ó! Bí amọ̀ ṣe rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.+ 7 Nígbà tí mo bá sọ pé màá fa orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan tu, tí mo sọ pé màá ya á lulẹ̀, tí màá sì pa á run,+ 8 bí orílẹ̀-èdè náà bá jáwọ́ nínú ìwà burúkú rẹ̀ tí mo kìlọ̀ fún un, èmi náà á pèrò dà* lórí àjálù tí mo ti sọ pé màá jẹ́ kó dé bá a.+ 9 Àmọ́, tí mo bá sọ pé màá kọ́ orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan, tí mo sọ pé màá gbìn ín, 10 tó bá ṣe ohun tó burú lójú mi, tí kò sì ṣègbọràn sí ohùn mi, ńṣe ni màá pèrò dà* nípa ohun rere tí mo sọ pé màá ṣe fún un.’

11 “Ní báyìí, jọ̀wọ́ sọ fún àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, mò ń ṣètò àjálù kan fún yín, mo sì ń pète ohun kan fún yín. Torí náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe.”’”+

12 Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Kò sí ìrètí!+ Torí pé tinú wa la máa ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ya alágídí, tí á sì máa ṣe ohun tí ọkàn burúkú rẹ̀ ń sọ.”+

13 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ẹ jọ̀wọ́, ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.

Ta ló ti gbọ́ irú èyí rí?

Wúńdíá Ísírẹ́lì ti ṣe ohun tó burú jù lọ.+

14 Ṣé yìnyín lè yọ́ kúrò lára àwọn àpáta tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Lẹ́bánónì?

Tàbí ṣé omi tútù tó ń ṣàn bọ̀ láti ibi tó jìnnà lè gbẹ?

15 Àmọ́ àwọn èèyàn mi ti gbàgbé mi.+

Torí pé wọ́n ń rú ẹbọ* sí àwọn ohun tí kò ní láárí,+

Wọ́n ń mú kí àwọn èèyàn fẹsẹ̀ kọ ní ọ̀nà wọn, àwọn ojú ọ̀nà àtijọ́,+

Láti rìn ní ọ̀nà gbágungbàgun, ọ̀nà tí kò dán, tí kò sì tẹ́jú,*

16 Láti sọ ilẹ̀ wọn di ohun àríbẹ̀rù+

Tí á sì di ohun àrísúfèé títí láé.+

Gbogbo ẹni tó bá ń gba ibẹ̀ kọjá á wò ó, ẹ̀rù á bà á, á sì mi orí rẹ̀.+

17 Màá tú wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù láti ìlà oòrùn.

Ẹ̀yìn ni màá kọ sí wọn, mi ò ní kọ ojú sí wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.”+

18 Wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gbìmọ̀ ibi sí Jeremáyà,+ nítorí òfin* kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn àlùfáà, ìmọ̀ràn kò sì ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn amòye, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn wòlíì. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ burúkú sí i,* kí a má sì fiyè sí ohun tó ń sọ.”

19 Fiyè sí mi, Jèhófà,

Sì fetí sí ohun tí àwọn alátakò mi ń sọ.

20 Ṣé ó yẹ kéèyàn fi ibi san ire?

Nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún ẹ̀mí* mi.+

Rántí bí mo ṣe dúró níwájú rẹ láti sọ ohun tó dáa nípa wọn,

Kí o lè yí ìbínú rẹ kúrò lórí wọn.

21 Torí náà, fi àwọn ọmọ wọn fún ìyàn,

Sì fi àwọn fúnra wọn fún idà.+

Kí àwọn ìyàwó wọn ṣòfò ọmọ, kí wọ́n sì di opó.+

Kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọkùnrin wọn,

Kí idà sì pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn lójú ogun.+

22 Jẹ́ kí a gbọ́ igbe ẹkún láti inú ilé wọn

Nígbà tí o bá mú àwọn jàǹdùkú* wá bá wọn lójijì.

Nítorí wọ́n ti gbẹ́ kòtò láti fi mú mi

Wọ́n sì ti dẹ pańpẹ́ fún ẹsẹ̀ mi.+

23 Ṣùgbọ́n, ìwọ Jèhófà,

O mọ gbogbo ètekéte wọn dáadáa, bí wọ́n ṣe fẹ́ pa mí.+

Má bo àṣìṣe wọn,

Má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò níwájú rẹ.

Jẹ́ kí wọ́n fẹsẹ̀ kọ níwájú rẹ+

Nígbà tí o bá dojú ìjà kọ wọ́n nínú ìbínú rẹ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́