ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 50
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Jósẹ́fù sin Jékọ́bù sí Kénáánì (1-14)

      • Jósẹ́fù fi dá àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú pé òun ti dárí jì wọ́n (15-21)

      • Jósẹ́fù darúgbó, ó sì kú (22-26)

        • Àṣẹ tí Jósẹ́fù pa nípa àwọn egungun rẹ̀ (25)

Jẹ́nẹ́sísì 50:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:4

Jẹ́nẹ́sísì 50:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 50:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2002, ojú ìwé 29-30

Jẹ́nẹ́sísì 50:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2002, ojú ìwé 29-30

Jẹ́nẹ́sísì 50:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “agbo ilé.”

Jẹ́nẹ́sísì 50:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 47:29-31
  • +Jẹ 48:21
  • +Jẹ 46:4; 47:29
  • +Jẹ 23:17, 18; 49:29, 30

Jẹ́nẹ́sísì 50:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 47:31

Jẹ́nẹ́sísì 50:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:21, 22

Jẹ́nẹ́sísì 50:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:27

Jẹ́nẹ́sísì 50:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:43; 46:29

Jẹ́nẹ́sísì 50:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Àwọn Ará Íjíbítì Ṣọ̀fọ̀.”

Jẹ́nẹ́sísì 50:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 47:29

Jẹ́nẹ́sísì 50:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 23:17, 18; 25:9, 10; 35:27; 49:29, 30

Jẹ́nẹ́sísì 50:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:18, 28; 42:21; Sm 105:17

Jẹ́nẹ́sísì 50:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:7, 9

Jẹ́nẹ́sísì 50:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:18
  • +Jẹ 45:5; Sm 105:17

Jẹ́nẹ́sísì 50:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 47:12

Jẹ́nẹ́sísì 50:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn ni pé, ó ṣe wọ́n bí ọmọ, ó sì ṣojúure sí wọn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 7:20
  • +Joṣ 17:1; 1Kr 7:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    9/15/1995, ojú ìwé 21

Jẹ́nẹ́sísì 50:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:31
  • +Jẹ 12:7; 17:8; 26:3; 28:13

Jẹ́nẹ́sísì 50:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:19; Joṣ 24:32; Heb 11:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2007, ojú ìwé 28

Jẹ́nẹ́sísì 50:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 50:2

Àwọn míì

Jẹ́n. 50:1Jẹ 46:4
Jẹ́n. 50:2Jẹ 50:26
Jẹ́n. 50:5Jẹ 47:29-31
Jẹ́n. 50:5Jẹ 48:21
Jẹ́n. 50:5Jẹ 46:4; 47:29
Jẹ́n. 50:5Jẹ 23:17, 18; 49:29, 30
Jẹ́n. 50:6Jẹ 47:31
Jẹ́n. 50:7Sm 105:21, 22
Jẹ́n. 50:8Jẹ 46:27
Jẹ́n. 50:9Jẹ 41:43; 46:29
Jẹ́n. 50:12Jẹ 47:29
Jẹ́n. 50:13Jẹ 23:17, 18; 25:9, 10; 35:27; 49:29, 30
Jẹ́n. 50:15Jẹ 37:18, 28; 42:21; Sm 105:17
Jẹ́n. 50:18Jẹ 37:7, 9
Jẹ́n. 50:20Jẹ 37:18
Jẹ́n. 50:20Jẹ 45:5; Sm 105:17
Jẹ́n. 50:21Jẹ 47:12
Jẹ́n. 50:231Kr 7:20
Jẹ́n. 50:23Joṣ 17:1; 1Kr 7:14
Jẹ́n. 50:24Ẹk 4:31
Jẹ́n. 50:24Jẹ 12:7; 17:8; 26:3; 28:13
Jẹ́n. 50:25Ẹk 13:19; Joṣ 24:32; Heb 11:22
Jẹ́n. 50:26Jẹ 50:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 50:1-26

Jẹ́nẹ́sísì

50 Jósẹ́fù sì ṣubú lé bàbá+ rẹ̀, ó sunkún lórí rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 2 Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn oníṣègùn, pé kí wọ́n tọ́jú òkú bàbá òun kó má bàa jẹrà.+ Àwọn oníṣègùn náà wá tọ́jú òkú Ísírẹ́lì, 3 wọ́n sì fi ogójì (40) ọjọ́ gbáko tọ́jú rẹ̀, torí iye ọjọ́ tí wọ́n fi ń tọ́jú òkú nìyẹn, kó má bàa jẹrà. Àwọn ará Íjíbítì sì ń sunkún torí Jékọ́bù fún àádọ́rin (70) ọjọ́.

4 Nígbà tí wọ́n ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ tán, Jósẹ́fù sọ fún àwọn òṣìṣẹ́* Fáráò pé: “Tí mo bá rí ojúure yín, ẹ bá mi sọ fún Fáráò pé: 5 ‘Bàbá mi mú kí n búra,+ ó ní: “Wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú.+ Kí o sin mí sí ibi ìsìnkú+ mi tí mo gbẹ́ ní ilẹ̀ Kénáánì.”+ Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n lọ sin bàbá mi, màá sì pa dà lẹ́yìn náà.’” 6 Fáráò fèsì pé: “Lọ sin bàbá rẹ, bó ṣe mú kí o búra.”+

7 Jósẹ́fù wá lọ sin bàbá rẹ̀, gbogbo ìránṣẹ́ Fáráò sì bá a lọ, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà+ ilé rẹ̀ àti gbogbo àgbààgbà ilẹ̀ Íjíbítì, 8 gbogbo agbo ilé Jósẹ́fù, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti agbo ilé bàbá+ rẹ̀. Àwọn ọmọ wọn kéékèèké, agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn nìkan ni wọ́n fi sílẹ̀ ní ilẹ̀ Góṣénì. 9 Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti àwọn tó ń gẹṣin tún bá a lọ, àwọn èèyàn náà pọ̀ gan-an. 10 Wọ́n wá dé ibi ìpakà Átádì, tó wà ní agbègbè Jọ́dánì, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ gidigidi níbẹ̀. Ọjọ́ méje ni Jósẹ́fù fi ṣọ̀fọ̀ bàbá rẹ̀. 11 Àwọn ọmọ Kénáánì, tó ń gbé ilẹ̀ náà rí wọn tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà Átádì, wọ́n sì sọ pé: “Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ àwọn ará Íjíbítì yìí o!” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Ebẹli-mísíráímù,* tó wà ní agbègbè Jọ́dánì.

12 Àwọn ọmọ Jékọ́bù ṣe ohun tó sọ fún wọn+ gẹ́lẹ́. 13 Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sin ín sínú ihò tó wà ní ilẹ̀ Mákípẹ́là, ilẹ̀ tó wà níwájú Mámúrè tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú.+ 14 Lẹ́yìn tó sin bàbá rẹ̀, Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó tẹ̀ lé e lọ sìnkú bàbá rẹ̀.

15 Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé bàbá àwọn ti kú, wọ́n sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Jósẹ́fù ń dì wá sínú, tí yóò sì san wá lẹ́san gbogbo ibi tí a ṣe sí i.”+ 16 Wọ́n wá ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù pé: “Kí bàbá rẹ tó kú, ó pàṣẹ pé: 17 ‘Ẹ sọ fún Jósẹ́fù pé: “Jọ̀ọ́, mo bẹ̀ ọ́, dárí àṣìṣe àwọn arákùnrin rẹ jì wọ́n, kí o sì gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá nígbà tí wọ́n ṣe ọ́ ní ibi.”’ Jọ̀ọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bàbá rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún. 18 Àwọn arákùnrin rẹ̀ náà wá, wọ́n wólẹ̀ síwájú rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Wò ó, a ti di ẹrú rẹ!”+ 19 Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni Ọlọ́run ni? 20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrò ibi lẹ ní sí mi,+ Ọlọ́run mú kó yọrí sí rere, kó lè dá ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn sí, bó ti ń ṣe lónìí.+ 21 Torí náà, ẹ má bẹ̀rù. Màá ṣì máa pèsè oúnjẹ+ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kéékèèké.” Bó ṣe tù wọ́n nínú nìyẹn, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.

22 Jósẹ́fù ń gbé ní Íjíbítì, òun àti agbo ilé bàbá rẹ̀. Ọjọ́ ayé Jósẹ́fù sì jẹ́ àádọ́fà (110) ọdún. 23 Jósẹ́fù rí ìran kẹta àwọn ọmọ+ Éfúrémù, pẹ̀lú àwọn ọmọ Mákírù,+ ọmọ Mánásè. Orúnkún Jósẹ́fù ni wọ́n bí wọn sí.* 24 Níkẹyìn, Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Mi ò ní pẹ́ kú, àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín,+ ó sì dájú pé yóò mú yín kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tó búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.”+ 25 Jósẹ́fù wá mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra, ó ní: “Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín. Kí ẹ kó egungun mi kúrò níbí.”+ 26 Ẹni àádọ́fà (110) ọdún ni Jósẹ́fù nígbà tó kú, wọ́n sì tọ́jú òkú rẹ̀ kó má bàa jẹrà,+ wọ́n wá gbé e sínú pósí ní ilẹ̀ Íjíbítì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́