Kíróníkà Kìíní
27 Iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí, àwọn olórí nínú àwọn agbo ilé, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ àti àwọn aláṣẹ wọn tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba+ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ àwọn àwùjọ tó ń wọlé àti àwọn tó ń jáde ní oṣooṣù ní gbogbo oṣù tó wà nínú ọdún; ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan.
2 Jáṣóbéámù+ ọmọ Sábídíẹ́lì ni olórí àwùjọ kìíní ti oṣù kìíní, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 3 Nínú àwọn ọmọ Pérésì,+ òun ni aṣáájú gbogbo olórí àwọn àwùjọ tí wọ́n yàn láti ṣiṣẹ́ ní oṣù kìíní. 4 Dódáì+ ọmọ Áhóhì + ni olórí àwùjọ tó wà fún oṣù kejì, Míkílótì ni aṣáájú, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 5 Olórí àwùjọ kẹta tí wọ́n yàn láti ṣiṣẹ́ ní oṣù kẹta ni Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà+ olórí àlùfáà, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 6 Bẹnáyà yìí jẹ́ jagunjagun tó lákíkanjú lára àwọn ọgbọ̀n (30) náà, òun ló ń bójú tó àwọn ọgbọ̀n (30) náà, Ámísábádì ọmọ rẹ̀ ló sì ń bójú tó àwùjọ rẹ̀. 7 Olórí àwùjọ kẹrin fún oṣù kẹrin ni Ásáhélì,+ arákùnrin Jóábù,+ Sebadáyà ọmọ rẹ̀ ló tẹ̀ lé e, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 8 Olórí àwùjọ karùn-ún fún oṣù karùn-ún ni Ṣámíhútì tó jẹ́ Ísíráhì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 9 Olórí àwùjọ kẹfà fún oṣù kẹfà ni Írà+ ọmọ Íkéṣì ará Tékóà,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 10 Olórí àwùjọ keje fún oṣù keje ni Hélésì+ tó jẹ́ Pélónì látinú àwọn ọmọ Éfúrémù, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 11 Olórí àwùjọ kẹjọ fún oṣù kẹjọ ni Síbékáì+ ọmọ Húṣà látinú àwọn ọmọ Síírà,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 12 Olórí àwùjọ kẹsàn-án fún oṣù kẹsàn-án ni Abi-ésérì + ọmọ Ánátótì+ látinú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 13 Olórí àwùjọ kẹwàá fún oṣù kẹwàá ni Máháráì+ ará Nétófà látinú àwọn ọmọ Síírà,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 14 Olórí àwùjọ kọkànlá fún oṣù kọkànlá ni Bẹnáyà+ ará Pírátónì látinú àwọn ọmọ Éfúrémù, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀. 15 Olórí àwùjọ kejìlá fún oṣù kejìlá ni Hélídáì ará Nétófà, láti ìdílé Ótíníẹ́lì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) ló sì wà nínú àwùjọ rẹ̀.
16 Àwọn aṣáájú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì nìyí: Nínú àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Élíésérì ọmọ Síkírì ni aṣáájú; nínú àwọn ọmọ Síméónì, Ṣẹfatáyà ọmọ Máákà; 17 nínú ẹ̀yà Léfì, Haṣabáyà ọmọ Kémúélì; nínú àwọn ọmọ Áárónì, Sádókù; 18 nínú ẹ̀yà Júdà, Élíhù+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin Dáfídì; nínú ẹ̀yà Ísákà, Ómírì ọmọ Máíkẹ́lì; 19 nínú ẹ̀yà Sébúlúnì, Iṣimáyà ọmọ Ọbadáyà; nínú ẹ̀yà Náfútálì, Jérímótì ọmọ Ásíríẹ́lì; 20 nínú àwọn ọmọ Éfúrémù, Hóṣéà ọmọ Asasáyà; nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, Jóẹ́lì ọmọ Pedáyà; 21 nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Gílíádì, Ídò ọmọ Sekaráyà; nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Jáásíélì ọmọ Ábínérì;+ 22 nínú ẹ̀yà Dánì, Ásárẹ́lì ọmọ Jéróhámù. Àwọn ni ìjòyè àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
23 Dáfídì kò ka àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sísàlẹ̀, nítorí pé Jèhófà ti ṣèlérí láti sọ Ísírẹ́lì di púpọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+ 24 Jóábù ọmọ Seruáyà bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn èèyàn, àmọ́ kò kà wọ́n parí; Ọlọ́run bínú sí Ísírẹ́lì* nítorí nǹkan yìí,+ a kò sì kọ iye náà sínú àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbà Ọba Dáfídì.
25 Ásímáfẹ́tì ọmọ Ádíélì ló ń bójú tó àwọn ibi ìṣúra ọba.+ Jónátánì ọmọ Ùsáyà ló ń bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí* ní pápá, ní àwọn ìlú, ní àwọn abúlé àti ní àwọn ilé gogoro. 26 Ẹ́síráì ọmọ Kélúbù ló ń bójú tó àwọn òṣìṣẹ́ inú pápá tó ń dáko. 27 Ṣíméì ará Rámà ló ń bójú tó àwọn ọgbà àjàrà; Sábídì tó jẹ́ Ṣífímì ló ń bójú tó àwọn ohun tó wá látinú àwọn ọgbà àjàrà fún ṣíṣe wáìnì. 28 Baali-hánánì ará Gédérì ló ń bójú tó àwọn oko ólífì àti àwọn igi síkámórè+ tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là;+ Jóáṣì ló sì ń bójú tó òróró. 29 Ṣítíráì ará Ṣárónì ló ń bójú tó àwọn ọ̀wọ́ ẹran tó ń jẹko ní Ṣárónì,+ Ṣáfátì ọmọ Ádíláì ló sì ń bójú tó àwọn ọ̀wọ́ ẹran tó wà ní àwọn àfonífojì.* 30 Óbílì ọmọ Íṣímáẹ́lì ló ń bójú tó àwọn ràkúnmí; Jedeáyà ará Mérónótì ló ń bójú tó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.* 31 Jásísì ọmọ Hágárì ló ń bójú tó àwọn agbo ẹran. Gbogbo wọn ni olórí tó ń bójú tó àwọn ohun ìní Ọba Dáfídì.
32 Jónátánì,+ ọmọ arákùnrin Dáfídì, jẹ́ agbani-nímọ̀ràn, ọkùnrin olóye ni, ó tún jẹ́ akọ̀wé, Jéhíélì ọmọ Hákímónì sì ń bójú tó àwọn ọmọ ọba.+ 33 Áhítófẹ́lì+ jẹ́ agbani-nímọ̀ràn ọba, Húṣáì+ tó jẹ́ Áríkì sì ni ọ̀rẹ́* ọba. 34 Lẹ́yìn Áhítófẹ́lì, ó kan Jèhóádà ọmọ Bẹnáyà+ àti Ábíátárì;+ Jóábù + sì ni olórí àwọn ọmọ ogun ọba.