ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Iṣẹ́ àmì mẹ́ta tí Mósè máa ṣe (1-9)

      • Mósè ní òun ò kúnjú ìwọ̀n (10-17)

      • Mósè pa dà sí Íjíbítì (18-26)

      • Mósè àti Áárónì tún jọ pàdé (27-31)

Ẹ́kísódù 4:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 2:13, 14

Ẹ́kísódù 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:9

Ẹ́kísódù 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 20:37
  • +Ẹk 3:16; 4:31

Ẹ́kísódù 4:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 12:10

Ẹ́kísódù 4:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:36

Ẹ́kísódù 4:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:30

Ẹ́kísódù 4:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnu mi wúwo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:12; Nọ 12:3; Jer 1:6; Iṣe 7:22

Ẹ́kísódù 4:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 24

    5/1/1999, ojú ìwé 28

Ẹ́kísódù 4:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “màá wà pẹ̀lú ẹnu rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 50:4; Mk 13:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    6/2020, ojú ìwé 7-8

Ẹ́kísódù 4:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1996, ojú ìwé 24-25

Ẹ́kísódù 4:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:59
  • +Ẹk 4:27

Ẹ́kísódù 4:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:28
  • +Jer 1:9

Ẹ́kísódù 4:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìwọ yóò jẹ́ àṣojú Ọlọ́run fún un.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 24

Ẹ́kísódù 4:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 8:5; 17:5, 6; Nọ 20:11

Ẹ́kísódù 4:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 2:18, 21; 18:1; Nọ 10:29

Ẹ́kísódù 4:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn tó ń wá ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 2:15

Ẹ́kísódù 4:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:9
  • +Ẹk 7:3; 8:15; 9:12; 11:10; Ro 9:17, 18
  • +Ẹk 7:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2020, ojú ìwé 2-3

Ẹ́kísódù 4:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:6; 14:2; Ho 11:1; Ro 9:4

Ẹ́kísódù 4:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:29

Ẹ́kísódù 4:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:22; 1Kr 21:16
  • +Jẹ 17:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 28

    9/15/1995, ojú ìwé 21-22

Ẹ́kísódù 4:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀bẹ tí wọ́n fi òkúta ṣe.”

  • *

    Tàbí “kọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 2:16, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 28

Ẹ́kísódù 4:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 28

Ẹ́kísódù 4:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:14
  • +Ẹk 3:1; 20:18; 24:16

Ẹ́kísódù 4:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:15
  • +Ẹk 4:8

Ẹ́kísódù 4:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:16; 24:1

Ẹ́kísódù 4:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:3, 6, 9

Ẹ́kísódù 4:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:18
  • +Jẹ 50:25
  • +Ẹk 1:14; 3:7; Di 26:6

Àwọn míì

Ẹ́kís. 4:1Ẹk 2:13, 14
Ẹ́kís. 4:3Ẹk 7:9
Ẹ́kís. 4:5Lk 20:37
Ẹ́kís. 4:5Ẹk 3:16; 4:31
Ẹ́kís. 4:6Nọ 12:10
Ẹ́kís. 4:8Iṣe 7:36
Ẹ́kís. 4:9Ẹk 4:30
Ẹ́kís. 4:10Ẹk 6:12; Nọ 12:3; Jer 1:6; Iṣe 7:22
Ẹ́kís. 4:12Ais 50:4; Mk 13:11
Ẹ́kís. 4:14Nọ 26:59
Ẹ́kís. 4:14Ẹk 4:27
Ẹ́kís. 4:15Ẹk 4:28
Ẹ́kís. 4:15Jer 1:9
Ẹ́kís. 4:16Ẹk 7:1, 2
Ẹ́kís. 4:17Ẹk 8:5; 17:5, 6; Nọ 20:11
Ẹ́kís. 4:18Ẹk 2:18, 21; 18:1; Nọ 10:29
Ẹ́kís. 4:19Ẹk 2:15
Ẹ́kís. 4:21Ẹk 7:9
Ẹ́kís. 4:21Ẹk 7:3; 8:15; 9:12; 11:10; Ro 9:17, 18
Ẹ́kís. 4:21Ẹk 7:22
Ẹ́kís. 4:22Di 7:6; 14:2; Ho 11:1; Ro 9:4
Ẹ́kís. 4:23Ẹk 12:29
Ẹ́kís. 4:24Nọ 22:22; 1Kr 21:16
Ẹ́kís. 4:24Jẹ 17:14
Ẹ́kís. 4:25Ẹk 2:16, 21
Ẹ́kís. 4:27Ẹk 4:14
Ẹ́kís. 4:27Ẹk 3:1; 20:18; 24:16
Ẹ́kís. 4:28Ẹk 4:15
Ẹ́kís. 4:28Ẹk 4:8
Ẹ́kís. 4:29Ẹk 3:16; 24:1
Ẹ́kís. 4:30Ẹk 4:3, 6, 9
Ẹ́kís. 4:31Ẹk 3:18
Ẹ́kís. 4:31Jẹ 50:25
Ẹ́kís. 4:31Ẹk 1:14; 3:7; Di 26:6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 4:1-31

Ẹ́kísódù

4 Àmọ́ Mósè fèsì pé: “Tí wọn ò bá gbà mí gbọ́ ńkọ́, tí wọn ò sì fetí sí mi?+ Torí wọ́n á sọ pé, ‘Jèhófà ò fara hàn ọ́.’” 2 Jèhófà bi í pé: “Kí ló wà lọ́wọ́ rẹ yẹn?” Ó fèsì pé: “Ọ̀pá ni.” 3 Ọlọ́run sọ pé: “Jù ú sílẹ̀.” Ó jù ú sílẹ̀, ló bá di ejò;+ Mósè sì sá fún un. 4 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ mú un níbi ìrù.” Ó nawọ́ mú un, ó sì di ọ̀pá lọ́wọ́ rẹ̀. 5 Ọlọ́run wá sọ pé, “Èyí á jẹ́ kí wọ́n gbà gbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù+ ti fara hàn ọ́.”+

6 Jèhófà tún sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, ki ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ rẹ lápá òkè.” Ó wá ki ọwọ́ bọ inú aṣọ rẹ̀. Nígbà tó yọ ọ́ jáde, ẹ̀tẹ̀ ti bò ó lọ́wọ́, ó sì funfun bíi yìnyín!+ 7 Ọlọ́run wá sọ pé: “Dá ọwọ́ rẹ pa dà sínú aṣọ rẹ lápá òkè.” Ó sì dá ọwọ́ rẹ̀ pa dà sínú aṣọ rẹ̀. Nígbà tó yọ ọ́ jáde nínú aṣọ, ó ti pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀! 8 Ó sọ pé: “Tí wọn ò bá gbà ọ́ gbọ́, tí wọn ò sì fiyè sí àmì àkọ́kọ́, ó dájú pé wọ́n á gba àmì kejì gbọ́.+ 9 Síbẹ̀, tí wọn ò bá gba àmì méjèèjì yìí gbọ́, tí wọn ò sì fetí sí ọ, kí o bu omi díẹ̀ látinú odò Náílì, kí o sì dà á sórí ilẹ̀, omi tí o bù nínú odò Náílì yóò sì di ẹ̀jẹ̀ lórí ilẹ̀.”+

10 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Má bínú, Jèhófà, mi ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa ṣáájú àkókò yìí àti lẹ́yìn tí o bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, torí ọ̀rọ̀ mi ò já geere,* ahọ́n mi sì wúwo.”+ 11 Jèhófà sọ fún un pé: “Ta ló fún èèyàn ní ẹnu, ta ló sì ń mú kó má lè sọ̀rọ̀, kó ya adití, kó ríran kedere tàbí kó fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Jèhófà ni? 12 Torí náà, lọ, màá wà pẹ̀lú rẹ bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,* màá sì kọ́ ọ ní ohun tí o máa sọ.”+ 13 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Má bínú, Jèhófà, jọ̀ọ́ rán ẹnikẹ́ni tí o bá fẹ́.” 14 Jèhófà wá bínú sí Mósè, ó sì sọ pé: “Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ+ tó jẹ́ ọmọ Léfì ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó sì ti ń bọ̀ wá bá ọ níbí báyìí. Tó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóò dùn.+ 15 Kí o bá a sọ̀rọ̀, kí o sì fi àwọn ọ̀rọ̀ náà sí ẹnu rẹ̀,+ màá wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,+ màá sì kọ́ yín ní ohun tí ẹ máa ṣe. 16 Yóò bá ọ bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, òun ló máa jẹ́ agbẹnusọ fún ọ, ìwọ yóò sì dà bí Ọlọ́run fún un.*+ 17 Kí o mú ọ̀pá yìí dání, kí o sì fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà.”+

18 Mósè wá pa dà sọ́dọ̀ Jẹ́tírò bàbá ìyàwó rẹ̀,+ ó sì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, mo fẹ́ pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi tó wà ní Íjíbítì kí n lè rí i bóyá wọ́n ṣì wà láàyè.” Jẹ́tírò sọ fún Mósè pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” 19 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè ní Mídíánì pé: “Pa dà lọ sí Íjíbítì, torí gbogbo àwọn tó fẹ́ pa ọ́* ti kú.”+

20 Mósè wá gbé ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó forí lé ilẹ̀ Íjíbítì. Mósè sì mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání. 21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Tí o bá dé Íjíbítì, rí i pé gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe lo ṣe níwájú Fáráò.+ Àmọ́, màá jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì ní jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.+ 22 Kí o sọ fún Fáráò pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ọmọ mi ni Ísírẹ́lì, àkọ́bí mi ni.+ 23 Mò ń sọ fún ọ pé, Jẹ́ kí ọmọ mi máa lọ kó lè sìn mí. Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kó lọ, màá pa ọmọkùnrin rẹ, àkọ́bí rẹ.”’”+

24 Lójú ọ̀nà ibi tí wọ́n dé sí, Jèhófà  + pàdé rẹ̀, ó sì fẹ́ pa á.+ 25 Ni Sípórà+ bá mú akọ òkúta,* ó dádọ̀dọ́* ọmọ rẹ̀, ó sì mú kí adọ̀dọ́ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ní: “Torí ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ lo jẹ́ fún mi.” 26 Torí náà, Ó jẹ́ kó lọ. Ìdádọ̀dọ́ náà ló mú kí obìnrin náà pè é ní “ọkọ ẹlẹ́jẹ̀” nígbà yẹn.

27 Jèhófà wá sọ fún Áárónì pé: “Lọ bá Mósè nínú aginjù.”+ Torí náà, ó lọ pàdé rẹ̀ ní òkè Ọlọ́run tòótọ́,+ ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu láti kí i. 28 Mósè sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹni tó rán an, fún Áárónì,+ ó sì sọ fún un nípa gbogbo iṣẹ́ àmì tó pa láṣẹ pé kó ṣe.+ 29 Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì lọ, wọ́n sì kó gbogbo àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ.+ 30 Áárónì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà+ níṣojú àwọn èèyàn náà. 31 Èyí mú kí àwọn èèyàn náà gbà á gbọ́.+ Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà ti yíjú sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ àti pé ó ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn,+ wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́