Jóòbù
24 “Kí ló dé tí Olódùmarè ò yan àkókò?+
Kí ló dé tí àwọn tó mọ̀ ọ́n kò rí ọjọ́ rẹ̀?*
4 Wọ́n ń fipá lé àwọn aláìní kúrò lọ́nà;
Àfi kí àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ láyé sá pa mọ́ fún wọn.+
5 Àwọn aláìní ń wá oúnjẹ kiri bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó+ nínú aginjù;
Wọ́n ń wá oúnjẹ kiri fún àwọn ọmọ wọn nínú aṣálẹ̀.
7 Ìhòòhò ni wọ́n ń sùn mọ́jú, wọn ò ní aṣọ;+
Wọn ò rí nǹkan kan fi bora nígbà òtútù.
8 Òjò orí òkè mú kí wọ́n rin gbingbin;
Wọ́n rọ̀ mọ́ àpáta torí wọn ò ríbi forí pa mọ́ sí.
9 Wọ́n já ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú;+
Wọ́n sì gba aṣọ aláìní láti fi ṣe ìdúró,+
10 Wọ́n fipá mú kí wọ́n máa rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ aṣọ,
Ebi sì ń pa wọ́n, bí wọ́n ṣe gbé àwọn ìtí ọkà.
11 Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láàárín àwọn ògiri ilẹ̀ onípele nínú ooru ọ̀sán gangan;*
Wọ́n ń tẹ àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ wọ́n.+
12 Àwọn tó ń kú lọ ń kérora nínú ìlú;
Àwọn tó fara pa gan-an* ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+
Àmọ́ Ọlọ́run ò ka èyí sí àìdáa.*
13 Àwọn kan wà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;+
Wọn ò mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀,
Wọn kì í sì í tẹ̀ lé àwọn òpópónà rẹ̀.
Ó sì ń bo ojú rẹ̀.
16 Wọ́n ń fọ́ ilé* nínú òkùnkùn;
Wọ́n ń ti ara wọn mọ́lé ní ọ̀sán.
Àjèjì ni wọ́n sí ìmọ́lẹ̀.+
17 Torí bákan náà ni àárọ̀ àti òkùnkùn biribiri rí fún wọn;
Wọ́n mọ àwọn ohun tó ń dẹ́rù bani nínú òkùnkùn biribiri.
18 Àmọ́ omi yára gbé wọn lọ.*
Ègún máa wà lórí ilẹ̀ wọn.+
Wọn ò ní pa dà sí àwọn ọgbà àjàrà wọn.
20 Ìyá rẹ̀* máa gbàgbé rẹ̀; ìdin máa fi ṣe oúnjẹ.
Wọn ò ní rántí rẹ̀ mọ́.+
A sì máa ṣẹ́ àìṣòdodo bí igi.
21 Ó ń rẹ́ àwọn àgàn jẹ,
Ó sì ń ni opó lára.
22 Ọlọ́run* máa fi okun rẹ̀ mú àwọn alágbára kúrò;
Bí wọ́n tiẹ̀ dìde, kò dájú pé wọ́n á ní ìyè.
24 A gbé wọn ga fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, wọn ò sí mọ́.+
A rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,+ a sì kó wọn jọ bíi gbogbo èèyàn yòókù;
A gé wọn kúrò bí orí ọkà.
25 Ta ló wá lè mú mi ní onírọ́,
Tàbí kó sọ pé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣòótọ́?”