Jóòbù
9 Jóòbù fèsì pé:
2 “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ló rí.
Àmọ́ báwo ni ẹni kíkú ṣe lè jàre tó bá bá Ọlọ́run ṣe ẹjọ́?+
3 Tí ẹnì kan bá tiẹ̀ fẹ́ bá A jiyàn,*+
Onítọ̀hún ò ní lè dáhùn ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) ìbéèrè tí Ó bá bi í.
4 Ọlọ́gbọ́n ni,* ó sì ní agbára gan-an.+
Ta ló lè ta kò ó, tí kò ní fara pa?+
5 Ó ń ṣí àwọn òkè nídìí* láìsí ẹni tó mọ̀;
Ó ń fi ìbínú dojú wọn dé.
6 Ó ń mi ayé tìtì kúrò ní àyè rẹ̀,
Débi pé àwọn òpó rẹ̀ ń gbọ̀n rìrì.+
7 Ó ń pàṣẹ pé kí oòrùn má ràn,
Ó sì ń dí ìmọ́lẹ̀ àwọn ìràwọ̀+ pa;
8 Òun nìkan na ọ̀run jáde,+
Ó sì ń rìn lórí ìgbì tó ga lórí òkun.+
9 Ó ṣe àgbájọ ìràwọ̀ Ááṣì,* Késílì* àti Kímà,*+
Pẹ̀lú àgbájọ ìràwọ̀ apá gúúsù ojú ọ̀run;*
10 Ó ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àwámáridìí,+
Àwọn ohun àgbàyanu tí kò ṣeé kà.+
11 Ó kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mi ò sì rí i;
Ó kọjá síwájú mi, àmọ́ mi ò dá a mọ̀.
12 Tó bá já nǹkan gbà, ta ló lè dá a dúró?
Ta ló lè bi í pé, ‘Kí lò ń ṣe?’+
14 Ǹjẹ́ kò wá yẹ kí n ṣọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu mi
Tí mo bá ń dá a lóhùn láti bá a jiyàn!
15 Tí mo bá tiẹ̀ jàre, mi ò ní dá a lóhùn.+
Mi ò lè ṣe ju pé kí n bẹ adájọ́ mi* pé kó ṣàánú mi.
16 Tí mo bá ké pè é, ṣé ó máa dá mi lóhùn?
Mi ò rò pé ó máa fetí sí ohùn mi,
17 Torí ó fi ìjì wó mi mọ́lẹ̀,
Ó sì mú kí ọgbẹ́ mi pọ̀ sí i láìnídìí.+
18 Kò jẹ́ kí n mí;
Ó ń fi àwọn ohun tó korò kún inú mi.
19 Tó bá jẹ́ ti agbára, òun ni alágbára.+
Tó bá jẹ́ ti ìdájọ́ òdodo, ó sọ pé: ‘Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò?’*
20 Tí mo bá jàre, ẹnu mi máa dá mi lẹ́bi;
22 Bákan náà ni gbogbo rẹ̀ rí. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé,
‘Bó ṣe ń pa aláìṣẹ̀* run ló ń pa ẹni burúkú run.’
23 Bí omi tó ya lójijì bá fa ikú òjijì,
Ó máa fi aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó ń dààmú.
24 A ti fi ayé lé ẹni burúkú lọ́wọ́;+
Ó ń bo ojú àwọn adájọ́ rẹ̀.
Tí kì í bá ṣe òun, ta wá ni?
25 Àwọn ọjọ́ mi wá ń yára ju ẹni tó ń sáré;+
Wọ́n sá lọ láìrí ohun tó dáa.
26 Wọ́n ń yára bí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi esùsú* ṣe,
Bí ẹyẹ idì tó já ṣòòrò wálẹ̀ láti gbé ohun tó fẹ́ pa.
27 Tí mo bá sọ pé, ‘Màá gbàgbé àròyé tí mo ṣe,
Màá tújú ká, màá sì múnú ara mi dùn,’
28 Ẹ̀rù á ṣì máa bà mí torí gbogbo ìrora mi;+
Mo sì mọ̀ pé o ò ní kà mí sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.
29 O máa sọ pé mo jẹ̀bi.*
Kí wá ni mo fẹ́ máa ṣe làálàá lásán fún?+
30 Tí mo bá fi omi yìnyín tó ń yọ́ wẹ ara mi,
31 O máa rì mí bọ kòtò,
Tí aṣọ mi pàápàá fi máa kórìíra mi.
32 Torí kì í ṣe èèyàn bíi tèmi tí màá fi dá a lóhùn,
Tí a fi jọ máa lọ sílé ẹjọ́.+