ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Ìmúrasílẹ̀ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì (1-18)

2 Kíróníkà 2:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:11; 1Kr 22:10
  • +1Ọb 7:1

2 Kíróníkà 2:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti máa ru ẹrù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:15
  • +1Ọb 5:16; 9:22; 2Kr 2:17, 18

2 Kíróníkà 2:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:1
  • +2Sa 5:11

2 Kíróníkà 2:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:7
  • +Ẹk 25:30
  • +Nọ 28:4
  • +Nọ 28:9
  • +Nọ 28:11
  • +Di 16:16

2 Kíróníkà 2:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 4

2 Kíróníkà 2:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:27; Ais 66:1; Iṣe 17:24

2 Kíróníkà 2:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:13, 14
  • +1Kr 22:15

2 Kíróníkà 2:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:6, 8; 2Kr 3:5
  • +1Ọb 10:11
  • +1Ọb 5:9
  • +1Ọb 5:14

2 Kíróníkà 2:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

  • *

    Báàtì kan jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:11

2 Kíróníkà 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:7
  • +2Kr 1:11, 12

2 Kíróníkà 2:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:13, 14; 2Kr 4:11-16

2 Kíróníkà 2:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 3:14
  • +Ẹk 31:2-5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 19

2 Kíróníkà 2:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 2:10

2 Kíróníkà 2:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:6, 8
  • +Joṣ 19:46, 48; Ẹsr 3:7
  • +1Ọb 5:9

2 Kíróníkà 2:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 8:7, 8
  • +1Kr 22:2

2 Kíróníkà 2:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti máa ru ẹrù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:17, 18; 1Kr 22:15
  • +1Ọb 5:15, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 19

Àwọn míì

2 Kíró. 2:1Di 12:11; 1Kr 22:10
2 Kíró. 2:11Ọb 7:1
2 Kíró. 2:21Ọb 5:15
2 Kíró. 2:21Ọb 5:16; 9:22; 2Kr 2:17, 18
2 Kíró. 2:31Ọb 5:1
2 Kíró. 2:32Sa 5:11
2 Kíró. 2:4Ẹk 30:7
2 Kíró. 2:4Ẹk 25:30
2 Kíró. 2:4Nọ 28:4
2 Kíró. 2:4Nọ 28:9
2 Kíró. 2:4Nọ 28:11
2 Kíró. 2:4Di 16:16
2 Kíró. 2:61Ọb 8:27; Ais 66:1; Iṣe 17:24
2 Kíró. 2:71Ọb 7:13, 14
2 Kíró. 2:71Kr 22:15
2 Kíró. 2:81Ọb 5:6, 8; 2Kr 3:5
2 Kíró. 2:81Ọb 10:11
2 Kíró. 2:81Ọb 5:9
2 Kíró. 2:81Ọb 5:14
2 Kíró. 2:101Ọb 5:11
2 Kíró. 2:121Ọb 5:7
2 Kíró. 2:122Kr 1:11, 12
2 Kíró. 2:131Ọb 7:13, 14; 2Kr 4:11-16
2 Kíró. 2:142Kr 3:14
2 Kíró. 2:14Ẹk 31:2-5
2 Kíró. 2:152Kr 2:10
2 Kíró. 2:161Ọb 5:6, 8
2 Kíró. 2:16Joṣ 19:46, 48; Ẹsr 3:7
2 Kíró. 2:161Ọb 5:9
2 Kíró. 2:172Kr 8:7, 8
2 Kíró. 2:171Kr 22:2
2 Kíró. 2:181Ọb 5:17, 18; 1Kr 22:15
2 Kíró. 2:181Ọb 5:15, 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 2:1-18

Kíróníkà Kejì

2 Sólómọ́nì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà,+ kí wọ́n sì kọ́ ilé* kan fún ìjọba òun.+ 2 Sólómọ́nì yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) ọkùnrin láti ṣe lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta ní àwọn òkè+ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) láti ṣe alábòójútó wọn.+ 3 Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù+ ọba Tírè pé: “Ohun tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi nígbà tí o kó igi kédárì ránṣẹ́ sí i láti fi kọ́ ilé* tí á máa gbé ni kí o ṣe fún mi.+ 4 Ní báyìí, mo fẹ́ kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, láti yà á sí mímọ́ fún un, láti máa sun tùràrí onílọ́fínńdà+ níwájú rẹ̀ àti láti máa kó búrẹ́dì onípele* síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà+ àti àwọn ẹbọ sísun ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́,+ ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀+ Jèhófà Ọlọ́run wa. Ohun tí Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn títí láé. 5 Ilé tí mo fẹ́ kọ́ náà máa tóbi, nítorí Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run míì lọ. 6 Ta ni agbára rẹ̀ gbé e láti kọ́ ilé fún un? Nítorí àwọn ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò lè gbà á,+ ta wá ni mí tí màá fi kọ́ ilé fún un? Àfi kí n kàn kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ibi tí a ó ti máa mú ẹbọ rú èéfín níwájú rẹ̀. 7 Ní báyìí, fi ọkùnrin oníṣẹ́ ọnà kan ránṣẹ́ sí mi, tó já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà, bàbà,+ irin, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú rírẹ̀dòdò àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, tó sì mọ bí a ti ń fín àwọn iṣẹ́ ọnà. Ó máa ṣiṣẹ́ ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ọnà mi tó já fáfá, àwọn tí Dáfídì bàbá mi ti pèsè sílẹ̀.+ 8 Kí o kó àwọn gẹdú igi kédárì, ti igi júnípà+ àti ti igi álígọ́mù+ láti Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí mi, nítorí mo mọ̀ dáadáa pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ bí a ṣe ń gé àwọn igi Lẹ́bánónì.+ Àwọn ìránṣẹ́ mi á bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣiṣẹ́+ 9 láti pèsè gẹdú tó pọ̀ gan-an sílẹ̀ fún mi, nítorí ilé tí mo fẹ́ kọ́ máa tóbi yàtọ̀. 10 Wò ó! Màá pèsè oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ,+ àwọn agégi tó máa gé igi náà, màá fún wọn ní: ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà,* ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ọkà bálì, ọ̀kẹ́ kan (20,000) báàtì* wáìnì àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) báàtì òróró.”

11 Hírámù ọba Tírè wá kọ̀wé ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì pé: “Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ó fi ọ́ ṣe ọba wọn.” 12 Hírámù sì sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé, nítorí ó ti fún Ọba Dáfídì ní ọlọ́gbọ́n ọmọ+ tó ní làákàyè àti òye,+ tó máa kọ́ ilé fún Jèhófà àti fún ìjọba òun fúnra rẹ̀. 13 Wò ó, mo ti rán ọkùnrin ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà kan sí ọ, ó ní òye, Hiramu-ábì+ ni orúkọ rẹ̀, 14 ó jẹ́ ọmọ obìnrin kan tó wá látinú ẹ̀yà Dánì, àmọ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ará Tírè; ó já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà, bàbà, irin, òkúta, igi gẹdú, òwú aláwọ̀ pọ́pù, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, aṣọ àtàtà àti aṣọ rírẹ̀dòdò.+ Ó lè fín oríṣiríṣi iṣẹ́ ọnà, ó sì lè ṣe iṣẹ́ ọnà èyíkéyìí tí wọ́n bá fún un.+ Ó máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà rẹ àti àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà olúwa mi Dáfídì bàbá rẹ. 15 Ní báyìí, kí olúwa mi fi àlìkámà,* ọkà bálì, òróró àti wáìnì tó ṣèlérí ránṣẹ́ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 16 A máa gé àwọn igi láti Lẹ́bánónì,+ bí èyí tí o nílò bá ṣe pọ̀ tó, a ó kó wọn wá sọ́dọ̀ rẹ ní àdìpọ̀ igi tó léfòó, a ó sì kó wọn gba orí òkun wá sí Jópà;+ wàá sì kó wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù.”+

17 Sólómọ́nì wá ka gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn ìkànìyàn tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ṣe,+ iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́tà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (153,600). 18 Nítorí náà, ó yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) lára wọn láti ṣe lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta+ ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) láti ṣe alábòójútó tí á máa kó àwọn èèyàn ṣiṣẹ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́