Ìsíkíẹ́lì
30 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Ẹ pohùn réré ẹkún, kí ẹ sì sọ pé, ‘Áà, ọjọ́ náà ń bọ̀!’
3 Torí ọjọ́ náà sún mọ́lé, àní ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+
Ọjọ́ ìkùukùu* ni yóò jẹ́,+ àkókò ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+
4 Idà yóò dojú kọ Íjíbítì, ìbẹ̀rù á sì bo Etiópíà nígbà tí òkú bá sùn ní Íjíbítì;
Wọ́n ti kó ọrọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti wó ìpìlẹ̀ rẹ̀.+
5 Etiópíà,+ Pútì,+ Lúdì àti onírúurú èèyàn náà*
Àti Kúbù, pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ májẹ̀mú,*
Idà ni yóò pa gbogbo wọn.”’
6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
‘Àwọn tó ń ti Íjíbítì lẹ́yìn pẹ̀lú yóò ṣubú,
Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò sì wálẹ̀.’+
“‘Idà ni yóò pa wọ́n ní ilẹ̀ náà, láti Mígídólì+ dé Síénè,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 7 ‘Wọ́n á di ahoro ju àwọn ilẹ̀ yòókù lọ, àwọn ìlú rẹ̀ á sì di ahoro ju àwọn ìlú yòókù lọ.+ 8 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá iná sí Íjíbítì, tí mo sì tẹ gbogbo àwọn tó bá a ṣàdéhùn rẹ́. 9 Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò rán àwọn òjíṣẹ́ nínú àwọn ọkọ̀ òkun, kí wọ́n lè mú kí Etiópíà tó dá ara rẹ̀ lójú gbọ̀n rìrì; ẹ̀rù yóò bà wọ́n ní ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀ wá sórí Íjíbítì, torí ó dájú pé ó máa dé.’
10 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò mú kí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ará Íjíbítì run.+ 11 Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn tó burú jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò wá láti pa ilẹ̀ náà run. Wọ́n á fa idà wọn yọ láti bá Íjíbítì jà, wọ́n á sì fi òkú àwọn tí wọ́n pa kún ilẹ̀ náà.+ 12 Èmi yóò sọ àwọn omi tó ń ṣàn láti odò Náílì+ di ilẹ̀ gbígbẹ, èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn èèyàn burúkú. Màá mú kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ di ahoro.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.’
13 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò tún pa àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* run, màá sì pa àwọn ọlọ́run Nófì*+ tí kò ní láárí run. Kò ní sí ọmọ Íjíbítì tó máa ṣe olórí* mọ́, màá sì mú kí ìbẹ̀rù wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 14 Màá pa Pátírọ́sì+ run, màá dá iná sí Sóánì, màá sì dá Nóò* lẹ́jọ́.+ 15 Màá bínú sí Sínì, ibi ààbò Íjíbítì, màá sì pa àwọn ará Nóò run. 16 Màá dá iná sí Íjíbítì; ìbẹ̀rù á bo Sínì, wọ́n á ya wọ Nóò, wọ́n á sì gbógun ti Nófì* ní ojúmọmọ! 17 Idà ni yóò pa àwọn géńdé ọkùnrin Ónì* àti Píbésétì, wọ́n á sì kó àwọn ìlú náà lọ sí oko ẹrú. 18 Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tehafínéhésì nígbà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà Íjíbítì níbẹ̀.+ Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò dópin,+ ìkùukùu* á bò ó, àwọn ìlú rẹ̀ yóò sì lọ sí oko ẹrú.+ 19 Èmi yóò dá Íjíbítì lẹ́jọ́, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
20 Ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ keje, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 21 “Ọmọ èèyàn, mo ti kán apá Fáráò ọba Íjíbítì; wọn ò ní dì í kó lè jinná tàbí kí wọ́n fi aṣọ wé e kó lè lágbára tó láti di idà mú.”
22 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò kọjú ìjà sí Fáráò ọba Íjíbítì,+ màá sì kán apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tó ti kán tẹ́lẹ̀ àtèyí tí kò tíì kán,+ màá sì mú kí idà já bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.+ 23 Màá wá tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.+ 24 Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára,*+ màá sì fi idà mi sí i lọ́wọ́.+ Èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora gidigidi bí ẹni tó ń kú lọ níwájú rẹ̀.* 25 Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára, àmọ́ ọwọ́ Fáráò yóò rọ; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fi idà mi sọ́wọ́ ọba Bábílónì, tó sì fì í, kó lè bá ilẹ̀ Íjíbítì jà.+ 26 Màá sì tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ wọn yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”