ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì (1-19)

        • Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Nebukadinésárì máa gbógun wá (10)

      • Ọlọ́run fòpin sí agbára Fáráò (20-26)

Ìsíkíẹ́lì 30:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ọbd 15
  • +Isk 32:7
  • +Sm 110:6

Ìsíkíẹ́lì 30:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 32:11, 12

Ìsíkíẹ́lì 30:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo àwọn tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì.”

  • *

    Ó lè jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbára lé Íjíbítì ló tọ́ka sí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 2:12
  • +Na 3:8, 9

Ìsíkíẹ́lì 30:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:18
  • +Jer 44:1
  • +Isk 29:10

Ìsíkíẹ́lì 30:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:19; Isk 29:12; 32:18

Ìsíkíẹ́lì 30:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:19; 32:11

Ìsíkíẹ́lì 30:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Hab 1:6
  • +Isk 29:5

Ìsíkíẹ́lì 30:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:3
  • +Isk 31:12

Ìsíkíẹ́lì 30:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

  • *

    Tàbí “Mémúfísì.”

  • *

    Tàbí “ọmọ ọba.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 43:12; 46:14
  • +Jer 46:5

Ìsíkíẹ́lì 30:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Tíbésì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:13, 14; Jer 44:1
  • +Jer 46:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2003, ojú ìwé 32

Ìsíkíẹ́lì 30:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2003, ojú ìwé 32

Ìsíkíẹ́lì 30:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Mémúfísì.”

Ìsíkíẹ́lì 30:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Heliopólísì.

Ìsíkíẹ́lì 30:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:8
  • +Jer 46:20; Isk 31:18
  • +Jer 46:19

Ìsíkíẹ́lì 30:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:25; Isk 29:3
  • +2Ọb 24:7; Jer 46:2
  • +Jer 46:21

Ìsíkíẹ́lì 30:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:12

Ìsíkíẹ́lì 30:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Èmi yóò fi kún agbára ọba Bábílónì.”

  • *

    Ìyẹn, níwájú ọba Bábílónì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:6
  • +Isk 32:11, 12

Ìsíkíẹ́lì 30:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:19, 20

Ìsíkíẹ́lì 30:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:12

Àwọn míì

Ìsík. 30:3Ọbd 15
Ìsík. 30:3Isk 32:7
Ìsík. 30:3Sm 110:6
Ìsík. 30:4Isk 32:11, 12
Ìsík. 30:5Sef 2:12
Ìsík. 30:5Na 3:8, 9
Ìsík. 30:6Isk 30:18
Ìsík. 30:6Jer 44:1
Ìsík. 30:6Isk 29:10
Ìsík. 30:7Jer 46:19; Isk 29:12; 32:18
Ìsík. 30:10Isk 29:19; 32:11
Ìsík. 30:11Hab 1:6
Ìsík. 30:11Isk 29:5
Ìsík. 30:12Isk 29:3
Ìsík. 30:12Isk 31:12
Ìsík. 30:13Jer 43:12; 46:14
Ìsík. 30:13Jer 46:5
Ìsík. 30:14Jẹ 10:13, 14; Jer 44:1
Ìsík. 30:14Jer 46:25
Ìsík. 30:18Isk 30:8
Ìsík. 30:18Jer 46:20; Isk 31:18
Ìsík. 30:18Jer 46:19
Ìsík. 30:22Jer 46:25; Isk 29:3
Ìsík. 30:222Ọb 24:7; Jer 46:2
Ìsík. 30:22Jer 46:21
Ìsík. 30:23Isk 29:12
Ìsík. 30:24Jer 27:6
Ìsík. 30:24Isk 32:11, 12
Ìsík. 30:25Isk 29:19, 20
Ìsík. 30:26Isk 29:12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 30:1-26

Ìsíkíẹ́lì

30 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Ẹ pohùn réré ẹkún, kí ẹ sì sọ pé, ‘Áà, ọjọ́ náà ń bọ̀!’

 3 Torí ọjọ́ náà sún mọ́lé, àní ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+

Ọjọ́ ìkùukùu* ni yóò jẹ́,+ àkókò ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+

 4 Idà yóò dojú kọ Íjíbítì, ìbẹ̀rù á sì bo Etiópíà nígbà tí òkú bá sùn ní Íjíbítì;

Wọ́n ti kó ọrọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti wó ìpìlẹ̀ rẹ̀.+

 5 Etiópíà,+ Pútì,+ Lúdì àti onírúurú èèyàn náà*

Àti Kúbù, pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ májẹ̀mú,*

Idà ni yóò pa gbogbo wọn.”’

 6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

‘Àwọn tó ń ti Íjíbítì lẹ́yìn pẹ̀lú yóò ṣubú,

Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò sì wálẹ̀.’+

“‘Idà ni yóò pa wọ́n ní ilẹ̀ náà, láti Mígídólì+ dé Síénè,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 7 ‘Wọ́n á di ahoro ju àwọn ilẹ̀ yòókù lọ, àwọn ìlú rẹ̀ á sì di ahoro ju àwọn ìlú yòókù lọ.+ 8 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá iná sí Íjíbítì, tí mo sì tẹ gbogbo àwọn tó bá a ṣàdéhùn rẹ́. 9 Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò rán àwọn òjíṣẹ́ nínú àwọn ọkọ̀ òkun, kí wọ́n lè mú kí Etiópíà tó dá ara rẹ̀ lójú gbọ̀n rìrì; ẹ̀rù yóò bà wọ́n ní ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀ wá sórí Íjíbítì, torí ó dájú pé ó máa dé.’

10 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò mú kí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ará Íjíbítì run.+ 11 Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn tó burú jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò wá láti pa ilẹ̀ náà run. Wọ́n á fa idà wọn yọ láti bá Íjíbítì jà, wọ́n á sì fi òkú àwọn tí wọ́n pa kún ilẹ̀ náà.+ 12 Èmi yóò sọ àwọn omi tó ń ṣàn láti odò Náílì+ di ilẹ̀ gbígbẹ, èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn èèyàn burúkú. Màá mú kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ di ahoro.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.’

13 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò tún pa àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* run, màá sì pa àwọn ọlọ́run Nófì*+ tí kò ní láárí run. Kò ní sí ọmọ Íjíbítì tó máa ṣe olórí* mọ́, màá sì mú kí ìbẹ̀rù wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 14 Màá pa Pátírọ́sì+ run, màá dá iná sí Sóánì, màá sì dá Nóò* lẹ́jọ́.+ 15 Màá bínú sí Sínì, ibi ààbò Íjíbítì, màá sì pa àwọn ará Nóò run. 16 Màá dá iná sí Íjíbítì; ìbẹ̀rù á bo Sínì, wọ́n á ya wọ Nóò, wọ́n á sì gbógun ti Nófì* ní ojúmọmọ! 17 Idà ni yóò pa àwọn géńdé ọkùnrin Ónì* àti Píbésétì, wọ́n á sì kó àwọn ìlú náà lọ sí oko ẹrú. 18 Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tehafínéhésì nígbà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà Íjíbítì níbẹ̀.+ Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò dópin,+ ìkùukùu* á bò ó, àwọn ìlú rẹ̀ yóò sì lọ sí oko ẹrú.+ 19 Èmi yóò dá Íjíbítì lẹ́jọ́, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”

20 Ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ keje, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 21 “Ọmọ èèyàn, mo ti kán apá Fáráò ọba Íjíbítì; wọn ò ní dì í kó lè jinná tàbí kí wọ́n fi aṣọ wé e kó lè lágbára tó láti di idà mú.”

22 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò kọjú ìjà sí Fáráò ọba Íjíbítì,+ màá sì kán apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tó ti kán tẹ́lẹ̀ àtèyí tí kò tíì kán,+ màá sì mú kí idà já bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.+ 23 Màá wá tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.+ 24 Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára,*+ màá sì fi idà mi sí i lọ́wọ́.+ Èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora gidigidi bí ẹni tó ń kú lọ níwájú rẹ̀.* 25 Èmi yóò fún ọwọ́ ọba Bábílónì lágbára, àmọ́ ọwọ́ Fáráò yóò rọ; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fi idà mi sọ́wọ́ ọba Bábílónì, tó sì fì í, kó lè bá ilẹ̀ Íjíbítì jà.+ 26 Màá sì tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ wọn yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́